Ọba méje wàjà láàrin oṣù mẹsàn l‘Oyo, ominú ń kọ mí - Gani Adams

Àwọn ọba wa kìí wàjà lemọ́lemọ́ bàyìí, àdánù ńlà ni fún Yorùbá – Gani Adams

Aseyin tilu Iseyin ati Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Aseyin and Gani Adams/Instagram

Ààrẹ Ona Kakanfo tilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams tí daro bi Aseyin tilu Iseyin, Ọba Abdulganiy Salahudeen Adekunle Oloogunebi, Ajinase kinni ṣe wàjà.

Atejade kan ti akọ̀wé feto ìròyìn rẹ, Kehinde Aderemi fisita lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí.

Bẹẹ ba gbagbe, Oriade náà ló dara pọ mọ àwọn baba nla rẹ lọjọ Aiku.

Ààrẹ woye pé kò dín ni Oriade méje tó ti wàjà nipinlẹ Oyo bayii laarin oṣù mẹsan.

Ààrẹ Gani Adams woye pe báwọn Oriade nílẹ̀ Yorùbá yìí ṣe n wàjà ni sisẹ n tẹle yii n yoo ṣe àkóbá fún ilẹ̀ Oodua.

Adams ni àdánù ńlá ni ikú Aseyin yìí jẹ fún ilẹ̀ Yorùbá, ti ẹja nla sì ti lọ ninu ibu fun Yoruba.

“Ta bá wo bí àwọn Oriade wa ṣe n re iwalẹ asa lẹ́nu lọọ lọọ yii, ominu yóò maa kọ yin pe ki lo de ati pe ki lo n fà á?

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yii si jẹ ìsòro nla to n koju ilẹ̀ Yorùbá lasiko yii èyí to n nípa ti ko dara lara wa yika ilẹ̀ Oodua.

Akoko yii ṣe pataki ninu itan Kaarọ Oojire nitori àwọn Oriade wa kii papoda lọna to ba ni lẹru bii eyi.“

Ààrẹ Gani Adams wá woye pe ipapoda Aseyin tún ti mú ká padanu ọba alaye to dantọ, ẹni tí igbe aye rẹ jẹ afihan iṣiṣẹ sin ọmọniyan.

Bakan naa lo ni Oriade to papoda naa ti mu idagbasoke alailẹgbẹ ba ìlú Iseyin, eyi to sọ ìlú náà di eyi to n yara dìdelẹ nipinlẹ Oyo.

Wo díẹ̀ lára àwọn ọba àlàyé tó wàjà ní ìpínlẹ̀ Oyo:

Lára awọn ori ade meje ti Gani Adams mẹnuba pe o waja ni sisẹ n tẹle, la ti rí Soun tilẹ̀ Ogbomoso ẹni tó wàjà lọ́jọ́ Kejìlá oṣù Kejìlá ọdún 2021 tó kọjá.

Ẹni kejì ni Olubadan tilẹ̀ Ibadan, ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogunguniso kinni, ẹni to dara pọ mọ àwọn baba nla rẹ lọjọ kejì oṣù Kinni ọdún 2022.

Oriade kẹta tí yóò waja laarin oṣù mẹsan nipinlẹ Oyo ni Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamide Olayiwola Adeyemi Kẹta.

Ọjọ́ ketalelogun oṣù kẹrin ọdún 2022 yìí ni Alaafin dara pọ mọ àwọn baba nla rẹ, tí wọn sì sìn sì Bara.

Lẹ́yìn èyí wa ni Aseyin tilu Iseyin yìí wàjà ni ọjọ́ Aiku, ọjọ́ kerinlelogun oṣù Keje ọdún 2022.