Ó ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà fòfin de okada gígùn nítorí ọ̀rọ̀ àbò

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency
Igbimọ to ga julọ lori ọrọ abo lorilẹede Naijiria ti kede pe o ṣeeṣe ki wọn gbẹsẹ leọkada ati iwakusa lorilẹede Naijiria gẹgẹbi ara igbesẹ lati dẹkun ọwọja awọn agbesunmọmi.
Igbimọ naa ni eyi lo lee di gbogbo awọn abuja ibi owo n gba wọle fun awọn oniṣẹ ibi naa.
Eyi wa lara ipade wọn eyi to waye labẹ idari aarẹ Muhammadu Buhari lọjọbọ.
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ lẹyin ipade wọn naa, agbẹjọro fun ijọba apapọ to tun jẹ minisita feto idajọ, Abubakar Malami ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati wo asopọ to wa laarin ọkada ati kusa wiwa ti wọn fura si pe o n pese owo fun rira nnka ijagun fawọn agbesunmọmi naa.
Amofin agba Malami ni awọn agbesunmọmi naa ti yipada kuro ni oniruuru ọna kotọ ti wọn fi n pawo wọle ki wọn to bọ sori iwakusa ati ijinigbepawo to wọpọ laarin wọn bayii.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency
O ni ijọba ko ṣai mọ irora ti ipinnu ti wọn n gbero naa yoo mu ba ọrọ aje araalu, paapaajulọ fifofin de ọkada gigun, amọṣa o ni igbesẹ naa ti di ọranyan lati lee daabo bo orilẹede Naijiria.
Awọn ẹgbẹ agbesunmọmi, paapaa lorilẹede Naijiria ti n da oju sọ gbigba akoso awọn agbegbe ti goolu gbilẹ si.








