Wo ànfààní tó jẹ bí ìjọba ṣe gbé NNPC fún aládàáni

Oríṣun àwòrán, Google
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi lede pe ileeṣẹ to n risi ọrọ epo bẹntirol lorilẹede Naijiria ti kuro ni ọwọ Ijọba bọ si ọwọ awọn aladani.
Ni ilu Abuja ni wọn ti ṣe ifilọlẹ rẹ, ti aarẹ Buhari si ni igbesẹ naa yoo pese epo bẹntirol ti awọn ọmọ Naijiria nilo fun wọn.
Bakan naa ni aare Buhari ni ileeṣẹ NNPC naa yoo si lee figa gbaga pẹlu awọn ẹka miran bii tirẹ lagbaye.
Amọ Ibeere ti ọpọ ọmọ Naijiria n beere ni kini anfaani to wa ninu bi ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ta ileese epo bẹntirol naa.
Ki ni anfaani to wa fun awọn ọmọ Naijiria ni tita NNPC?
Onimọ ni ẹka ileeṣẹ epo bẹntirol, Ọjọgbọn Ahmaf Isa Haruna ni igbesẹ ijọba ko ni yi awọn oludari ẹka naa pada tabi gba iṣẹ lọwọ wọn, to si ni ko si ti ohun tuntun kan ti yoo waye tabi yipada pẹlu tita rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o ni kani awọn aladani ti yoo gba ileeṣẹ naa yoo tun awọn ikọ iwapo ṣe ni pẹlu adehun, boya nkan mere mere ko ba jade lati ibẹ fun awọn ọmọ Naijiria.
O ni amọ o ṣeeṣe ko jẹ niṣe ni awọn aladani naa yoo si maa gbe epo wọle lati oke okun,eleyii ti onimọ naa ni ko lee mu oriire kankan dani fun awọn ọmọ Naijiria.
Onimọ naa ni bi ẹka ina mọnamọna se di bo ṣe da lẹyin ti ijọba taa naa ni yoo ri fun ọrọ epo bẹntirol naa.
Amọ onimọ miran, Kailani Mohammed ninu ero tirẹ ni eleyii yoo mu ki epo bentirol wa yanturu ni iye owo ti ko ni kan ni ni eegun ẹyin fun awọn ọmọ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, twitter
Amọ onimọ miran, Kailani Mohammed ninu ero tirẹ ni eleyii yoo mu ki epo bentirol wa yanturu ni iye owo ti ko ni kan ni ni eegun ẹyin fun awọn ọmọ Naijiria.
Bakan naa lo ni igbesẹ tuntun yii yoo fun awọn oludoko lati oke okun laaye lati wa da iṣẹ silẹ ni Naijiria, paapaa ni ẹka ina mọnamọna, eto ẹkọ, eto ilera ati oju ọna.
O fikun un pe ọpọlọpọ nkan meremere ni yoo mu wa fun awọn ọmọ Naijiria bi ijọba se gbe le awọn aladani lọwọ.
Bakan naa ni yoo fun awọn ọmọ Naijiria ni anfaani lati ra ‘’Shares’’ ni NNPC gẹgẹ bi oludokowo nibẹ.
Amọ awọn onimọ naa ni ijọba orilẹede Naijiria naa lo ṣi ni ileeṣẹ NNPC, ti wọn yoo si ma a ṣakoso rẹ, amọ wọn ti taa fun awọn oludokowo.
‘Orilẹede Naijiria lo ni epo bẹntirol julọ ni Afrika’
Iwadii fihan pe orilẹede Naijiria lo ni epo bẹntirol julọ ni Afrika pẹlu barrel miliọnu meji aabọ ti wọn n pese ni ojumọ labẹle.
Eyi mu ki Naijiria jẹ orilẹede kẹfa ni gbogbo agbaye to ni epo bẹntirol julọ.
Amọ iwa jẹgudujẹra ati wọbia ni ẹka naa, pẹ̣lu aisi papako iwa epo ati titun epo da si bẹntirol lọna igbalode (refineries) lo doju ẹka naa bolẹ lati bii ọgọta ọdun ṣẹyin.
















