"Ọ̀dọ́bìnrin kò gbọdọ̀ lọ́ sílẹ̀ òkèèrè mọ́ láì gba àṣẹ ìjọba"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba orilẹede Chad ti paṣẹ pe ko si ọdọmọbinrin kankan to gbọdọ kuro lorilẹede naa mọ lọ silẹ okeere lai gba aṣẹ lọwọ ijọba.
Minisita fun ọrọ abo ilu ati iwọlewọde lorilẹede naa, ọgagun Idriss Dokony Adiker lo sọ eyi di mimọ.
Ọgagun Idriss Dokony Adiker ni ijọba gbe igbesẹ yii lati lee dẹkun wahala “bi awọn ọdọbinrin ṣe n jade kuro lorilẹede naa lọ silẹ okeere nibi ti wọn ti n fi wọn ṣe oniruuru owo kotọ gbogbo.”
Ikede naa fofin de awọn ileeṣẹ irinna ofurufu atawọn ajọ eleto irinna gbogbo lorilẹede naa pe wọn ko gbọdọ gbe ọdọbinrin kankan rinrinajo lọ si oke okun.
Awọn ajọ ajafẹtọ obinrin gbogbo lorilẹede Chad ni wọn ti gbarata si aṣẹ tuntun yii eyi ti wọn sọ pe o tako ẹtọ ọmọniyan fun awọn ọdọbinrin lorilẹede naa.
Ajọ ajafẹ̀tọ obinrin The Chadian Women’s Right League ni tirẹ tọka si aṣẹ naa gẹgẹbi eyi to n dẹyẹ si ẹya kan.
Ajọ naa ni awọn ọdọmọkunrin lorilẹede naa pẹlu n ko si panpẹ awọn afinisowo kotọ gbogbo.
Gẹgẹbi abajade iwadi ajọ global initiative against transnational crime ṣe sọ, iye awọn to n fi eeyan ṣe owo kotọ lorilẹede naa ti pọ si laarin ọdun diẹ sẹyin.
Paapaa julọ pẹlu iye awọn to n gba aala orilẹede naa pẹlu Sudan wọ orilẹede Libya.
















