Mo fi àṣeyọrí mi sọrí Serubawon ẹgbọ́n mi, n kò ní fayọ̀ fọ́ ìgbẹ́kẹ̀lé aráàlú - Adeleke

Adeleke n tẹwọ gba iwe ẹri aṣeyege idibo lọwọ alaga ajọ INEC lẹkun iwọ ooru gusu NAijiria, Ọjọgbọn Kunle Ajayi

Ademola Adeleke tí wọ́n dìbò yàn ni ọjọ kẹrindinlogun osu keje ọdun 2022 gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, ti gba ìwé ẹ̀rí rmo yege gẹ́gẹ́ bi ẹni tí wọ́n dìbò yàn.

Olú iléeṣẹ́ àjọ elétò ìdìbò INEC to wa ni Osogbo ni eto naa ti waye.

Ní ọjọ́ Àìkú ni àjọ INEC kéde senator Ademola Jackson Adeleke gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí wọ́n dìbò yàn fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun.

Professor Kunle Àjàyí ti o je Alakoso ati alabojuto iléeṣe àjọ eleto idibo INEC ni ẹkùn Osun, Ogun, ati Ipinle Oyo, lo se akoso eto gbigba iwe ẹri aṣeyege idibo naa.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ gbe iwe ẹri aṣeyege idibo le igbakeji gomina ti ilu ṣẹṣẹ yan nibẹ, Ọmọọba Kọla Adewusi lọwọ.

Igbakeji gomina ti wọn ṣẹṣẹ yan l'Ọṣun, Ọmọọba Adewusi n tẹwọ gba iwe ẹri aṣeyege idibo lọwọ alaga ajọ INEC lẹkun iwọ ooru gusu Naijiria, Ọjọgbọn Kunle Ajayi

Eto naa n waye lẹyin wakati mejilelaadọrin ti ajọ naa kede Sẹnetọ Ademọla adeleke gẹgẹbii olubori eto idibo sipo gomina to waye lọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2022.

Adeleke bori pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna irinwo le mẹta ati ọdunrun le mọkanlelaadọrin (403, 371).

Adeleke n tẹwọ gba iwe ẹri aṣeyege idibo lọwọ alaga ajọ INEC lẹkun iwọ ooru gusu Naijiria, Ọjọgbọn Kunle Ajayi

Ninu ọrọ akọsọ rẹ, Senator Ademola Adeleke sọ pe ohun fí aseyori Oriire naa sọri ẹgbọn ohun, oloogbe Senator Isiaka Adeleke ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ PDP ni ipinle Osun.

Bakan naa niAdemọla Adeleke ṣalaye pe ohun ko ṣai mọ riri igbẹkẹle awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati fi oun jẹ gomina wọn, nitori naa oun ko ni fi ayọ fọ igbẹkẹle naa bi o ti wulẹ ko mọ.