Ó ṣeéṣe kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ó dìbò lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, other
Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ni o ṣeeṣe o ki awọn ẹlẹwọn kaakiri ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria o lanfani ati dibo lasiko idibo apapọ ọdun 2023.
Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni awọn ti n ṣe agbeyẹwo ọna ti awọn ẹlẹwọn lorilẹede Naijiria yoo fi lee dibo lasiko idibo ọdun 2023.
Ọjọgbọn Yakubu ni asiko to ki awọn ẹlẹwọn bẹrẹ si ni janfani yii paapaajulọ lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nilu Benin City gbe idajọ kalẹ lati gbe ẹtọ awọn ẹlẹwọn lati dibo lẹyin.
Alaga ajọ INEC ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n gbalejo ọga agba ileeṣẹ to n mojuto ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria,
Ninu onka kan to jade lọdun 2020, ẹgbẹrun mẹtalelaadọrin ati ẹẹdẹgbẹrin o le mẹrindinlọgbọn (73, 726) ẹlẹwọn lo wa lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Haliru Nababa lọfisi rẹ nilu Abuja.
Alaga ajọ INEC ni amuyẹ marun un ni iwe ofin orilẹede Naijiria la kalẹ fun ẹnikẹni lati dibo lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, inec
Akọkọ ni pe o gbọdọ jẹ ọmọ Naijiria, ekeji ni pe ko gbọdọ kere ju ẹni ọdun mejidinlogun lọ. Amuyẹ kẹta ni pe o gbọdọ wa, gbe tabi ṣiṣẹ nijọba ibilẹ to ti forukọ silẹ.
Amuyẹ kẹrin ni ki o fi ara rẹ han fun oṣiṣẹ ajọ INEC to n mojuto iforukọ silẹ oludibo ti amuyẹ karun un si jẹ pe ko gbọdọ ni ipenija ofin kankan lọrun.
Bakan naa lo sọrọ lori awọn koko bii ibi ti wọn yoo gbe ibudo idibo si, bi awọn ẹgbẹ oṣelu yoo ṣe maa polongo idibo wọn nibẹ ati bi awọn alamojuto idibo yoo ṣe maa ri aye wọ ọgba ẹwọn lasiko idibo.












