Agbébọn pá èèyàn méje tó ń bọ̀ láti ayẹyẹ ìgbéyàwó

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Awọn afurasi agbẹbọn kan ti ṣe ikolu si agbegbe abule kan ti orukọ rẹ jẹ Otulu, ti wọn si sina bolẹ fun eeyan meje, nigbati wọn tibi igbeyawo kan bọ ni ipinlẹ Imo.
Otulu ni o wa ni ijọba ibile iwọ oorun Oru to wa ni ipinlẹ Imo
Awọn afurasi agbebọn naa ni ọpọ ni igbagbọ pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ẹsọ alabọ, Ebubeagu
Ekan kan ilu Olutu , Nnamdi Agbor, ẹni to ba Ileeṣẹ BBC sọrọ, ni eeyan meje ni o ba iṣẹlẹ na lọ, ti wọn meta si ti di ẹni awati.
Agbor ni awọn eeyan ni awọn nani wọn ti ibi igbeyawo kan bọ nigbati awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ Ebubeagu yi ibọn lu wọn, ti o si pa eeyan meje sile .

Oríṣun àwòrán, Screenshot
“Inu bi ọpọlọpọ wa bayi nitori awọn eeyan ko ṣe nkankan lati jẹbi iku lọwọ ẹgbẹ Ebugbeagu nitori wọn bọ lati ibi igbeyawo kan ni. A ti fi ọrọ yi to Kọmisana ileeṣẹ olopaa ipinlẹ Imo leti, ti DPO agbegbe ọhun si ti bẹrẹ iwadi lori ikọlu naa.”
O tẹsiwaju pe o to eeyan meta ti awọn si n wa kiri nitori iṣẹlẹ naa.
“Lẹyin ikọlu ni a lati bẹrẹ sin ni wa awọn orukọ wọn yii, Uchenna Orjiribeka, Chido Ekesinachi ati Nnamdi Ekesinachi.”
“Awọn to wa ni ile wosan ni Chigozie Obinwa, Ozioma, Chikere Anyadioha, Ifechi Ekesinachi, Emeka Ekesinachi, Aboy Ihegboro ati Chijindu".
Nǹkan tí Iléesẹ́ Olọ́pàá sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ naa
Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, Mike Abattam ni iroyin na ti n tẹ awọn lọwọ, ti awọn si ti bẹrẹ iwadi lori ikọlu na.
Abattam ni awọn ko le sọ pato nkan to sẹlẹ sugbọn iwadi yoo fi idi iṣẹlẹ naa han.”
“A ko le sọ pe nkan bayi lo sẹlẹ tabi bi o ṣe waye sugbọn a ti bẹrẹ iwadi, ti ba pari iwadi tan, a ma sọrọ lori ikọlu naa”















