Buhari, Atiku fí ọ̀rọ̀ síta lórí bí Adeleke ṣe borí ní ìdìbò Osun; Ohun tí wọ́n sọ rèé

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ki Gomina ti wọn dibo yan nipinlẹ Osun tii ṣe oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP, Ademola Adeleke ku oriire gẹgẹ bo ṣe jawe olubori nibi idibo ipinlẹ Osun.
Aarẹ buhari sọ pe idibo naa fi ohun ti ijọba awa ara wa n jẹ han lootọ to fi mọ bibọwọ fun ifẹ awọn araalu.
Aarẹ Buhari tun kan sara si ọna ti wọn gba ṣe eto idibo ni ipinlẹ naa gẹgẹ bi afihan ihuwa bi agba ati ifarajin gbogbo awọn ti ọrọ kan lati fi iṣẹ ati ilana eto idibo to dara han ni Naijiria.
Bakan naa ni buhari fi kun un pe oun gbero lati fi ipa rere lelẹ nipa idibo lorilẹede Naijiria.
Ademola to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo 403,371 ninu gbogbo ibo Osun ajọ INEC si ti kede pe oun lo jawe olubori.
Pẹlu ibo yii ni Ademola fi fẹyin gomina to wa lori alefa lọwọlọwọ, Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ oṣelu APC gbo ilẹ.
Atiku, Saraki naa fesi lori iṣẹgun Adeleke

Oríṣun àwòrán, OTHER
"Imọlẹ ti de si Osun", eyi ni ohun ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar kọkọ sọ jade gẹgẹ bo ṣe ki Ademola Adeleke ku oriire.
Bo ṣe n kii ku oriire naa lo tun n kan sara si awọn eeyan ti wọn jọ para pọ lati jẹ ki aṣeyọri naa ṣee ṣe.
Eyi to pọ ju ninu ọrọ rẹ ni kíkí awọn awọn ara ipinlẹ Osun ku oriire gẹgẹ bi o ṣe sọ.
Bakan naa, Aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ ri ato tun jẹ oloye ẹgbẹ oṣelu PDP, bukola Saraki ni tirẹ sọ pe Adeleke ni imọ kikun nipa ẹkọ to ti kọ lọdun 2018 - nigba to kọkọ gbegba ibo gomina ipinlẹ Osun to si wa ṣiṣẹ takun takun lati kọ ṣiṣe iṣẹ pọ kaakiri ipinlẹ rẹ ati orilẹede.

Saraki ni ẹgbẹ oṣelu awọn yoo lo iru ọgbọn amulo yii lasiko idibo aarẹ ti yo waye lọdun 2023. Lara awọn oloṣelu mii to tun ti fi ọrọ ikini wọn sita si Ademola Adeleke ni Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo.
Bakan naa, igbakeji oludije gomina ni Eko lẹgbẹ oṣelu PDP, Funke Akindele naa ti fi ọrọ ikini rẹ sita.
















