Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹ́ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ńlá lórí ìyanṣẹ́lódì ASUU

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, NLC ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣe ìwọ́de ńlá tako ìyanṣẹ́lódì èyí tí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì gùnlé.
NLC ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n àti ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Keje, ọdún 2022 ni àwọn yóò ṣe ìwọ́de ńlá káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí bí ìjọba kò ṣe kọbi ara sí ìyanṣẹ́lódì tí ASUU gùnlé.
Ẹ ó rántí pé NLC ti fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọjọ́ mọ́kànlélógún láti fi wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìyánṣẹ́lódì tó ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Keji, ọdún 2022.
Ní báyìí tí ọjọ́ mọ́kànlélógún náà ti pé tí kò sì sí ìgbésẹ̀ kan pàtó láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ láti wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní àwọn yóò ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, Ayuba Wabba ní gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́rẹ̀rìndínlógójì tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí àti olú ìlú ilẹ̀ wa ni ìwọ́de náà yóò ti wáyé.
Wabba nínú àtẹ̀jáde kan ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹfà ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹnukò pé àwọn gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ padà sí ilé ẹ̀kọ́.
Ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ni ASUU ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì aláìní gbèdéke lórí àdéhùn ọdún 2009 tí wọ́n fẹnukò pẹ̀lú ìjọba ṣùgbọ́n tí ìjọba kò ì tíì ṣàmúṣẹ rẹ̀.










