Ademola Adeleke: Ta ni olùdíje gómìnà fún PDP tó gbégbá orókè láti tukọ̀ ìpínlẹ́ Osun

Kii se iroyin tuntun mọ pe Sẹnatọ Ademola Adeleke, tii se oludije sipo gomina nipinlẹ Osun lo jawe olubori ninu eto idibo to waye lọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun osu keje ọdun 2022.
Adeleke lo ni apapọ esi ibo to to 403,371 ninu eto idibo naa lati fi ẹyin alatako rẹ, gomina Adegboyega Oyetola janlẹ, ẹni to ni apapọ ibo 375,027.
Bẹẹ ba si gbagbe, igba keji ree ti Ademola Adeleke yoo dije fun ibo gomina nipinlẹ Osun.
- Ohun tóo ní láti mọ̀ nípa àwọn olùdíje Gómìnà Osun tí ẹnu ń kùn jù rèé
- Mo bèrè lọ́jọ́ Debate pé níbo ni Helicopter wà, ọ̀rọ̀ tí Oyetola sọ, mo fẹ́ fèsì báyìí - Ademola Adeleke
- Wo ohun mẹ́fà tó yé kí o mọ̀ nípa Gomìnà Gboyega Oyetola níbí..-
- Yemi Osinbajo ti ṣiṣẹ́ abẹ, kò sì gbòdì lọ lára rẹ̀ - Dókítà
- Wò gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì tó délé ẹjọ́ lẹ́yìn Baba Ijesha
O ti kọkọ tiraka saaju lọdun 2018 amọ to fidi rẹmi, eyi to mu ki gomina Oyetola to jawe olubori di gomina.
Bakan naa, ẹgbọn Ademola, eyiun Sẹnatọ Isiaka Adeleke naa ti jẹ gomina ri nipinlẹ Osun, ko to di oloogbe.
Wo koko ohun to yẹ ko mọ nipa Ademola Adeleke:
- A bí Ademola Jackson Adeleke Ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù karún-un, ọdun 1960 ní ìpínlẹ̀ Enugu ní ìdílé senatọ̀ Raji Ayoola àti Nnena Esther Adeleke ní ìlú Ede
- Eya iran Igbo ni iya re Nnena je
- O bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Methodist ní Surulere àti Nuwarudeen ní Ikire
- Bákan náà ló lọ ile iwe Seventh Day àti ile iwe Musalim Grammar ni ìlú Ede ti o sí kọ ẹkọ́ ìmọ nípa ọdaran ní Jacksonville State University Alabama USA
- Ademola to jẹ aburo baba olorin takasufe, Davido ro dẹdẹ, bẹẹ lo kan dudu nibi ayẹyẹ ikẹkọjade ni fasiti to ti gboye l'Amerika
- O jẹ́ adarí àgbà ní ile iṣẹ́ Pacific Holdings Limited láti 2001 sí 2006 àti Quicksilver Courier Company ní Atlanta, Georgia láti 1985 sí 1989
- Ademola Adeleke bẹ̀rẹ̀ òṣèlú ní ọdún 2007 ó sì dí senato tó ń sojú ẹkùn ìwọ̀-oòrùn Oṣun lẹ̀yìn ikú ẹgbọn rẹ̀ Isiaka Adetunji Adeleke tó jẹ́ Gomìnà alágbádá àkọkọ.
- Wọn fi ẹsun kan Adeleke pe ko ni iwe ẹri oniwe mẹwa ati pe, se lo se ayederu iwe ẹri abajade nile ẹkọ girama to lọ, eyiun Testimonia ati WAEC rẹ
- Iwe Testimnonial ti Adeleke fisilẹ fun ajọ INEC ninu idibo ọdun 2018 ni deeti ogunjọ osu Keje ọdun 1988 wa lara rẹ








