Nollywood In Court: Baba Ijesa, Baba Suwe, Yetunde Wunmi àtàwọn òṣèré tíátà tó ṣe ẹjọ́

Awọn oṣere

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Pupọ ninu awọn gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, ti ọpọlọpọ alatilẹyin ati awọn ololufẹ wọn kaakiri agbaye ni ifẹ si, ti wọn si ni ibọwọ fun amọ ti ọrọ ile ẹjọ n gbe wọn saye lakoko yii.

Ọpọlọpọ igba ni awọn gbajugbaja naa ti ja awọn ọlọlufẹ wọn kulẹ latari awọn iwa ti ko daa ti wọn hu, ti o si ran ọpọlọpọ laarin wọn si ẹwọn lati lọ jẹ iya ẹṣẹ wọn.

BBC Yoruba ṣe akojọpọ awọn gbajugbaja oṣere tiata ni orilẹede Naijiria ti wọn ti ṣagbako ẹwọn tabi ri ogun ile ẹjo nitori iwa ibajẹ ti wọn hu.

Baba Ijesha nile ẹjọ

Baba Ijesha:

Ile-ẹjọ kan ni Ikeja ran gbajugbaja oṣere Olanrewaju James Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, lọ si ẹwọn ọdun marun un leyin ti ile ẹjo kede pe o jẹbí esun ifipa banilopọ to ṣe si ọmọ ọdun merinla kan.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo da Baba Ijesha lẹbi fun iwa aiṣedede si ọmọ kan, ilọkulọ ibalopọ, ati igbiyanju ifipabanilopọ.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Babatunde Omidina

Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajugbaja oṣere Yoruba ti o ti di oloogbe, Babatunde Omidina, ti ọpọ mọ si Baba Suwe ni ọwọ ajọ NDLEA tẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ti wọn si fi ẹsun pe o gbe ogun oloro kuro lorilẹede Naijiria.

Baba Suwe lo ọpọlọpọ oṣe ni ahamọ ki ile ẹjo to wa pada daa lare pe ko jẹbi ẹsun ti ajọ naa fi kan an.

Taiwo Akinwande (Wunmi)

Yetunde Wunmi

Oríṣun àwòrán, Yetunde Wumi

Lọdun 2007, gbajugbaja oṣere obinrin oni tiata, Taiwo Akinwade ti ọpọ mọ si Wummi, ni ile ẹjo ran lọ si ẹwọn ọdun mẹta lẹyin ti ile ẹjọ kede pe o jẹ bi ẹsun gbigbe ogun oloro.

Aworan Taiwo Akinwade

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ni papakọ ofurufu, Murtala Muhammed ni ọwọ ajọ NDLEA ti tẹ gbajugaja osere tiata naa nigba ti o fẹ gbera lọ si ilu London.

O to oogun oloro mejilelaadọrun ti ajọ NDLEA ba lara arabinrin Taiwo Akinwade nigba naa.

Bimbo Akinsanya

aworan bimbo akinsanya

Oríṣun àwòrán, Screenshoy

Gbagbajugba osere tiata, Bimbo Akinsanya ni o ri ogun ile ejọ latari bi wọn ṣe fi ẹsun ipaniyan kan an.

Bukola Babalola

Aworan bukky black

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gbajugbaja osere Bukola Babalola, 'Bukky Black' ni wọn fi ẹsun ipaniyan kan pe o ṣeku pa ọmọ onilẹ kan ni agbegbe Ikorodu ni ipinlẹ Eko.

Babalola ni wọn gbe lo si ile ẹjọ ti o si lo ọpọlọpọ ọsẹ ni atimolẹ.

Oṣerebinrin yii ko fibẹ foju han mọ ninu awọn fiimu ati pe ko gbe ni orilẹede Naijrira mọ.

Tayo Odueke(Sikiratu Sindodo)

Aworan tayo odueke

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Tayo Odueke jẹ gbajugbaja osere tiata ti ọpọ mọ si Sikiratu Sidondo, ni ọdun diẹ sẹyin ni wọn fi ẹsun iṣekupa ọmọdekunrin kan kan an.

Ẹni ọdun kan ati oṣu mẹrin ni ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Daramola ni agbegbe Adeniyi Jones ni ipinlẹ Eko.

Ọwọ olopaa tẹ oṣere ọhun, o si lo ọpọlọpọ ọsẹ ni agọ wọn, ki awọn molẹbi ọmọ to ni awọn o ṣe ẹjọ mọ ati pe ko jẹbi ẹsun naa.

Ibinabo Fiberesima

aworan Ibinabo Fiberesima,

Oríṣun àwòrán, Sceenshot

Gbajugbaja oṣere fiimu ni ede Gẹẹsi, Ibinabo Fiberesima, pẹlu awọn to lọ si ẹwọn lẹyin ti o fi ọkọ ayokẹlẹ rẹ ṣeku pa Dokita Giwa Suraj latari bi o ṣe wa ọkọ naa ni iwakuwa.

Ile ẹjo giga ipinlẹ Eko wa ran ọmọbirin oṣere tiata naa lọ si ẹwọn ọdun marun un.

Ṣugbọn, ile ẹjo da gbajugbaja oṢere tiata naa sile lẹyin ti o san owo to to milọnu meji naira.

Sauce Kid

aworan Babalola Falemi

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Babalola Falemi, olorin ti ọpọ mọ si Sauce Kid ni ọwọ Ọlọpaa tẹ lorilẹede Amẹrika fun ẹsun ole jija, ti o si ri ẹwọn ọdun meji he.

Iroyin sọ pe olorin naa ji kaadi banki mẹẹdogun, ti o si parọ 'PIN' wọn lati fi igba owo lẹnu ẹrọ 'ATM.'

Sauce Kid ji owo to to ẹgbẹrun mẹẹdọgun owo dọla.