Baba Suwe: Ohun tí ojú Baba Suwe rí rèé lákàtà àjọ NDLEA lórí ẹ̀sùn pé ó gbé òògùn olóró

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọjọ ti a ba ku laa dere, eniyan o sunwọn laaye.
Aye gbọ, ọrun mọ nigba ti gbajugbaja osẹre adẹrinpoṣonu, Babajide Omidina ti ọpọ mọ si Baba Suwe wọ kaa ilẹ sun l'Ọjọbọ ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2021.
Baba Suwe si ti wa lori idubulẹ aisan fun igba pipẹ ki ọlọjọ to de.
- Baba Suwe ti kú tipẹ́ ṣaájú kí gbogbo èèyàn tó mọ̀- Àbúrò Baba Suwe
- Wo àwọn gbajúmọ̀ aláwàdà Yorùbá méje tó ti kú saájú Baba Suwe
- Baba Suwe fẹ́ sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kò tó kú àmọ́ Ọlọ́run kò gbà fun - Suwe Ayodele
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
- Àlàyé ọlọ́pàá Osun rèé lórí ọ̀nà tí Rahmon Adedoyin gbà ká ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínu fọ́nrán ohùn tó lu ayélujára pa
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
Ọpọ eeyan si lo gbagbọ pe aisan Baba Suwe bẹrẹ lẹyin igba ti ajọ NDLEA to n gbogun ti gbigbe oogun oloro mu un ti wọn si ju si atimọle.
Ko si tun yẹ ka gbagbọ pe Baba Suwe rele ẹjọ fun igba pipẹ lori ọrọ yii eyi tawọn eeyan ni o tun dakun ilera rẹ.
Bi irianjo rẹ si ahamọ ajọ to n gbogun ti gbigbe oogun oloro naa si se bẹrẹ ree:

Oríṣun àwòrán, AFP
Irin ajo Baba Suwe ree pẹlu ajọ NDLEA:
Ajọ NDLEA ti Baba Suwe mọle lori ẹsun pe o gbe oogun oloro
Loṣu kẹwaa ọdun 2011 ni iroyin jade pe ajọ NDLEA ti mu Baba Suwe ni papakọ ofurufu ilu Eko lori ẹsun pe o gbe oogun oloro.
Ajọ NDLEA ni kọmputa lo gbe jade pe egbogi oloro wa nikun Baba Suwe ti o fẹ gbe lọ si ilu Paris lorilẹede France.
Bi wọn ṣe fi Baba Suwe si atimọle jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan tori bi wọn ṣe fẹran rẹ gẹgẹ bi adẹrinpoṣonu.
Ajọ naa ni ẹrọ to n se ayẹwo awọn arinrinajo soke okun lo ri egboogi oloro ninu Baba Suwe, ti wọn si se gbogbo ohun to yẹ lati mu ko yagbẹ.
Erongba wọn ni pe boya o le su egbogi oloro mọ igbẹ amọ ko yagbẹ, eyi ti ko jẹ ki ẹri wa nilẹ lati mu rele ẹjọ pe lootọ ni Baba Suwe gbe oogun oloro.
Idi si ree ti ọpọ eeyan se maa n pe Baba Suwe ni Adimeru o yagbẹ ti.
Baba Suwe kuro latimọle NDLEA lẹyin ti wọn mu lori ẹsun gbigbe oogun oloro
Ajọ NDLEA tu Baba Suwe silẹ ni ahamọ wọn ninu oṣu kọkanla lẹyin ti wọn ti i mọle lori ẹsun pe o gbe oogun oloro si ikun rẹ.
Lẹyin to lo ọsẹ mẹta latimọle NDLEA, wọn fi Baba Suwe silẹ lẹyin ti ko yagbẹ.
Awọn ololufẹ rẹ fi ijo ati ilu pade rẹ lẹyin to jade kuro ni ahamọ NDLEA.
Owo to le ni ẹgbẹrun mẹta dọla $3,300 ni wọn fi gba beeli Baba Suwe.
Bamidele Aturu to jẹ agbẹjọro Baba Suwe sọ fun ile ẹjọ pe oriṣiiriṣii ayẹwo ni ajọ NDLEA ṣe lori rẹ, lati se afihan oogun oloro to gbe amọ ti wọn ko si ri nkan kan.
Ile ẹjọ paṣẹ pe ki NDLEA san miliọnu mẹẹdọgbọn (₦25m) owo gba mabinu fun Baba Suwe
Lẹyin ọ rẹyin, ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko paṣẹ pe ki ajọ NDLEA san miliọnu mẹẹdọgbọn naira fun Baba Suwe gẹgẹ bi owo gba ma binu.
Adajọ Yetunde Idowu paṣẹ pe ajọ NDLEA gbọdọ san owo naa fun Baba Suwe laarin ọjọ mọkanlelogun.
Ọgọrun miliọnu naira ni agbẹjọro Baba Suwe beere fun un, ki ile ẹjọ to paṣẹ pe ki ajọ NDLEA san miliọnu mẹẹdọgbọn.
Adajọ ṣalaye ninu idajọ rẹ pe ajọ NDLEA ko ni ẹri to daju lati fidi rẹ mulẹ pe Baba Suwe gbe oogun oloro sikun.
Sugbọn titi ti Baba Suwe fi jade laye lọjọ Aje, ọjọ kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021, adẹrinposonu naa ko ri kọbọ gba lọdọ Ajọ NDLEA.
N jẹ o see se ki Baba Suwe si wa laye to ba jẹ pe NDLEA san miliọnbu mẹẹdọgbọ fun?
Lori ijagudu yii si ni agbẹjọro Baba Suwe, Bamidele Aturu jade laye, ti ko si si ẹni ti yoo ran alawada naa lọwọ mọ, lati gba ẹtọ rẹ pada lọwọ ijọba.
Ni awọn asiko yii, Baba Suwe ti dubulẹ aisan, to si n rele iwosan ni ojoojumọ fun itọju ara rẹ, bakan naa lo nilo owo lati setọju ara rẹ.
Akoko kan tiẹ wa, tawọn ẹlẹyinju aanu kede pe oloogbe naa nilo iranwọ owo fun itọju ara rẹ, ti ẹbi ara, ọrẹ atawọn onitiata si n dide lati sugba rẹ.
Bakan naa lo lọ si oke okun fun itọju amọ sibẹ aisan yii ko gbọ wiwo titi ti ọlọjọ fi de ba a lẹyin ọdun mẹwa to la ẹsun ajọ NDLEA kọja.
Ṣugbọn ohun ti ọpọ eeyan wa n sọ bayii ni pe boya Baba Suwe ko ba ye, ti ko ba si wa laye lonii, to ba jẹ pe o ri miliọnu mẹẹdọgbọn naira owo gba ma binu ti ile ẹjọ ni ki ajọ NDLEA san fun un gba ni.
Eyi o wu ka wi, Ọlọrun mọ ju ẹda lọ.




















