Osun 2022: Buhari ti kí Adeleke kú oríire, Oyetola, gbà fún Ọlọ́run, bá aláyọ̀ yọ̀ - Olajengbesi

Oríṣun àwòrán, Adegboyega Oyetola and Ademola Adeleke
Pelumi Olajengbesi tii se agbẹjọro, ajafẹtọẹni ati ọmọ ẹgbẹ oselu PDP tisọrọ nipa esi ibo gomina to waye nipinlẹ Osun.
Olajengbesi lero rẹ gba gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola nimọran lati tete ki ẹni to jawe olubori ninu ibo naa ku oriire gẹgẹ bi aarẹ Muhammadu Buhari ti se.
Ajafẹtọẹni naa ni ohun gbogbo yoo dara ti gomina ipinlẹ Osun naa ba tete gba fun Ọlọrun lori abajade esi ibo naa.
- Buhari, Atiku fí ọ̀rọ̀ síta lórí bí Adeleke ṣe borí ní ìdìbò Osun; Ohun tí wọ́n sọ rèé
- Tèmi yé mi, àlàyé rèé lórí ìdí tí mo ṣe dúró ti Oyetola - Oluwo
- Wo àwọn gómìnà tó tí jẹ ní ìpínlẹ̀ Osun
- “APC, ẹ má kábàámọ̀ lórí èsì ìbò Osun, àtúntò la nílò fọ́jọ́ ìwájú”
- Àwọn alágbára yí ìbò ní 2018 àmọ́ Ọlọ́run fi ‘Hammer’ jàn wọ́n mọ́lẹ̀ ní 2022 - Aráàlú
Agbẹjọro naa fikun pe bii igba ti eeyan n fi akoko sofo ni, ti Oyetola ba fi morile ile ẹjọ lori esi ibo naa nitori ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa gan ko le gbe lẹyin Oyetola lori esi ibo naa.
Ọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun osu Keje ọdun 2022 ni eto idibo gomina waye nipinlẹ Osun, ti ajọ INEC si kede pe oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP lo jawe olubori ninu ibo naa.

À ń ṣàgbéyẹ̀wò èsì ìdìbò lọ́wọ́, ẹ̀yin ènìyàn ẹ fọkàn balẹ̀ - Oyetola

Oríṣun àwòrán, Google
Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó tún jẹ́ olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Osun lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje, Gboyega Oyetola ti sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí ètò ìdìbò náà wáyé.
Oyetola tó fìdí rẹmi sọ́wọ́ olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Ademola Adeleke ti rọ gbogbo àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ láti fọkán balẹ̀.
Gómìnà Oyetola tó sọ̀rọ̀ gba tẹnu agbẹnusọ rẹ̀ Ismail Omipidan lọ́jọ́ Àìkú ní àwọn ń wòye èsì ìdìbò tí INEC kéde lọ́wọ́.
- Wo àwọn gómìnà tó tí jẹ ní ìpínlẹ̀ Osun
- Tèmi yémi, àlàyé rèé lórí ìdí tí mo ṣe dúró ti Oyetola - Oluwo
- Àwọn alágbára yí ìbò ní 2018 àmọ́ Ọlọ́run fi ‘Hammer’ jàn wọ́n mọ́lẹ̀ ní 2022 - Aráàlú
- “APC, ẹ má kábàámọ̀ lórí èsì ìbò Osun, àtúntò la nílò fọ́jọ́ ìwájú”
- Wò gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì tó délé ẹjọ́ lẹ́yìn Baba Ijesha
Ó rọ àwọn ènìyàn láti ṣe sùúrù kí wọ́n sì máa tẹ̀lé òfin àti ìlànà gbogbo, kí wọ́n má domi àláfíà ìlú rú káàkiri ìpínlẹ̀ náà.
Ó ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn yóò fèsì sí èsì ìdìbò náà ní kété tí àwọn bá ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn èsì ìdìbò náà tí wọ́n sì foríkorí fikùnlukùn lórí bí ètò ìdìbò náà ṣe lọ.
Ó ní kí àwọn ènìyàn máa bá iṣẹ́ òòjọ́ wọn lọ láìsí ìdìwọ́ kankan.
Bákan náà ló rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ri dájú pé àwọn ènìyàn kò tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.

Òṣìṣẹ́ ikọ̀ Amotekun kankan kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ níbi ètò ìbò gomina Osun- Ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, @Amotekun
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ile ẹjọ gíga kan ni ìlú Osogbo ti pàṣẹ fún àjọ eleto ìdìbò, INEC.
Ileejo naa ni pe INEC ko gbọdọ lo awọn oṣiṣẹ ikọ aláàbò Amọtẹkun nínú eto idibo gomina tí yóò wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ile ẹjọ ọhun tún ní Amọtẹkun ko gbọdọ ko oṣiṣẹ rẹ kankan jáde láti lọwọ nínú ètò ìdìbò náà.
Àṣẹ ilé ẹjọ yìí ló n wáyé lẹyìn ìpẹ́jọ́ kan.
Iwe aṣẹ naa ni "Olujẹjọ kínní (INEC) ko gbọdọ bẹrẹ fún lílò oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun kankan lásìkò eto idibo náà titi ti ẹjọ to wà lórí ọrọ náà yóò fi yanjú."
"Bákan náà, ìkọ Amọtẹkun ko gbọdọ ran oṣiṣẹ rẹ kankan jade láti ṣiṣẹ abo nibi eto idibo náà, titi ti ẹjọ tó wà nílẹ̀ yóò fi yanjú."
"Ile ẹjọ yìí sún ẹjọ náà sì ogunjọ, oṣù, Keje, ọdún 2022 yìí."
- Ohun tóo ní láti mọ̀ nípa àwọn olùdíje Gómìnà Osun tí ẹnu ń kùn jù rèé
- Kini 'pen' l'ede Yoruba?
- Njẹ́ ọ̀rọ̀ ipò gómínà Osun ní 2022 kò fẹ́ ẹ̀ da ẹbí Adeleke rú báyìí?
- Osun 2022: Kò sí ìjà mọ́, Adeleke àti Babayemi ṣetán láti jọ ṣiṣẹ́ papọ̀
- Kini Yoruba ‘international passport’?
- Kini 'Staircase' ni Yoruba?
Kíni INEC so?
Ẹwẹ, nigba to n sọrọ lórí àṣẹ náà, adari àjọ INEC n'ipinlẹ Osun, Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji sọ pé àwọn tí gba ìwe ẹjọ náà.
Àmọ́ ọ ni kii ṣe iwa INEC lati máa lo ìkọ Amotekun fun ètò ìdìbò.
Raji ni àwọn ẹṣọ abo ti ijoba àpapọ̀ nìkan ni INEC máa n lọ fún ètò idibo, nítorí náà, ọrọ ètò ìdìbò ko kan Amotekun niwọn igba to jẹ pe ìjọba ìbílẹ̀ ni wọn n ṣiṣẹ fún.

Oríṣun àwòrán, @Amotekun
"Ẹ dira ògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀ lọ síbi ìdìbò yín" adari Amọtẹkun pàṣẹ fáwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ni Oṣun
Oro Amotekun ninu idibo Osun bayii
Bi ero idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ọsun ku Si dẹdẹ bayii, ajọ agbofinro Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọsun ti rọ àwọn oṣiṣẹ rẹ latio rii daju pe wọn dira pẹlu awọn oogun iṣembaye to daju bi wọn ba n lọ sibi ibo l'ojo Abamẹta.
Àṣẹ yii jẹyọ ninu atẹjade kan ti ọgá agba ajọ alaabo Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, alagba Amitolu Shittu fi sita lati salaye fun gbogbo awọn oṣiṣẹ amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun.
Amitolu Shittu rọ awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọsun pe wọn kò gbọdọ wọ aṣọ iṣẹ lọ sibi ibo bikòṣe aṣọ ara. Bakan naa lo ṣalaye pe kaadi idibo wọn nikan ni ki wọn mu dani.
O ni lootọ ìjọba ipinlẹ lo gba wọn ṣiṣẹ ṣugbọn ki wọn ríi dájú pe wọn ko fi eyi hùwa ni waduwadu lasiko idibo naa.
" Ẹ ríi daju pe ẹ mu gbogbo awọn ajẹbiidan ogun abẹnugọngọ dani l'asiko idibo naa.
Bakan naa ni ki ẹ rii daju ẹ n fi gbogbo awọn ohun ti oju yin ba n to ni ibùdó idibo yin to awọn agbofinro.
yooku bii ọlọpaa, DSS at'awọnileesẹ agbofinro miran leti."

Oríṣun àwòrán, @Amotekun
Àṣẹ yii n waye lẹyin wakati diẹ ti ileẹjọ kan gbe idajọ kalẹ lọkọ Ẹti pe ajọ amọtẹkun ko laṣẹ labẹ ofin lati ṣiṣẹ igbofinro lasiko idibo.

















