Osun state election 2022: Kosun state election 2022 ní PDP ni yóò borí nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, facebook/Southwest-Frontier
Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipa yiyan ọmọ oye ni ipinlẹ Osun, awọn oludije mejeji to n du ipo gomina ni awọn ti sẹtan láti ṣe iṣẹ́ papọ.
Ademola Adeleke ati Ọmọba Dotun Babayemi ni wọn kede pé opin ti de ba irinjiyan tí o waye ninu ẹgbẹ osẹlu PDP ni Ìpinlẹ Osun lẹyin tí ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni "Eyitayo Jegede reconciliation committee" ṣe abewo sì ipinlẹ naa .
Ninu atẹjade ti ẹgbẹto n ri si imura idibo fun Ọmọba Dotun Babayemi fi sita lọjọ Aje, wọn ni nnkan to kan awọn ni bi ẹgbẹ oselu PDP yoo ṣe bori ninu eto ìdibo gomina to n bọ ni ipinlẹ Osun.
- Idají ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
- A ò sọ pé ọmọ orílẹ̀ èdè Niger ni àwọn afurasí ta mú ní Sokoto - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Odunlade Adekola fakọyọ níbi àmì èyẹ AMVCA, ohun tí akẹgbé rẹ̀ Bukunmi sọ rèé
- Yorùbá ẹ fúnra, àwọn tó ṣekú pa Deborah fẹ́ dá ògún sílẹ̀ ni, wọn kò gbọdọ̀ lọ láì jìyà -Gani Adams
- Láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi, kò sí obìnrin tí mo kọnu ìfẹ́ sí tí kò gbà fún mi -Efuoma Amos
- Wo àwọn órílẹ̀èdè mẹ́wàá ti ojú ọjọ́ wọn tí n gbóná jan-jan ju ti tẹ́lẹ̀ lọ
- Àwọn ọlọ́kadà dáná sun 'Sound engineer' l'Eko lẹ́yìn àríyànjiyàn lórí ₦100
- Wo àwon ìròyìn òfégè nípa ikú Deborah Ṣamuel àti ìkọlù sí Bishop Kukah
- Tọkọtaya gbé ọmọ wọn lọ sílé ẹjọ́ torí àì bímọ lẹ́yìn ìgbéyàwó
Ẹgbẹ naa ni awọn wa fun alaafia ati ifọwọsowọpọ ẹgbẹ lati borí awọn alatako ninu eto ìdibo gomina to n bọ.
Atẹjade naa ni "A ri awọn to daa fun ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Osun, ti a si gbagbọ pe pẹlu suuru, a oo borí àwọn alatako."
Ẹgbẹ Dotun Babayemi wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP ni Ìpinlẹ Osun lati ma dẹkun ìṣẹ ribiribi ti wọn n se lati ri pe ẹgbẹ oṣelu PDP bori ninu eto ìdibo ọhun.
Ki ni Ademola Adeleke sọ?
Bakan naa, Sẹnetọ Ademola Adeleke ninu ọrọ rẹ ni ipade naa ni o wa ninu imura oun lati ri pe ẹgbẹ oselu PDP ipinlẹ Osun wa ni iṣọkan ninu igbiyanju lrẹ ati borí alatako ninu eto ìdibo to ń bo.
Adeleke ni oun ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ lati borí ninu eto ìdibo gomina to n bo.
"Bibori ẹgbẹ oselu APC jẹ nnkan pataki fun awa ọmọ ẹgbẹ PDP tori pe oun ni kọkọrọ fun wa ninu eto ìdibo apapọ ni ọdun 2023.
Ipade naa ni Eyitayo Jegede darí pẹlu awọn agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Osun.














