Couple takes son to court: Wo tọkọtaya gbé ọmọ wọn lọ sílé ẹjọ́ torí àì bímọ lẹ́yìn ìgbéyàwó

Airinjina, ni airi abuke Ọ̀kẹ́rẹ́.
Tọkọtaya kan ni ipinlẹ Uttarakhand, ni orile-ede India ti gbe ọmọkunrin kan ṣoṣo ti wọn bi lọ sile ẹjọ́, nitori pe ko tii bimọ lẹyin ọdun mẹ́fà to ṣe igbeyawo.
Sanjeev ati Sadhana Prasad, ẹni ọdún mọkanlelọgọta ati mẹtadinlọgọta, sọ pe gbogbo owo ti awọn ni laye ati ọ̀run, ni àwọn fi tọ ọmọkunrin naa dagba, gbọ bukaata eto ẹ̀kọ́ rẹ to fi di awakọ baalu, ati igbeyawo alarinrin ti awọn ṣe fun.
- Ilé tí mo kọ́ ni Ìlànà Omo Oòduà, mi ò lè sá kúrò níbẹ̀ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Okùnrin tó bá ọmọ ọdún 16 lòpọ̀, tó tún ya fọ́tò ìhòhò rẹ̀ dèrò àtìmọ́lé l’Ogun
- Mr Macaroni, Serap, Oby Ezekwesili, Amnesty International faraya lórí Deborah tí wọ́n pa ní Sokoto lórí ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ lódì sí Ànọ́bì
- Ìpàdé ìjọba Nàìjíríààti ASUU lórí ìyanṣẹ́lódì tún forí ṣánpọ́n
- Àwọ̀n ènìyàn rò pé wèrè, ajínigbé ni mí, àmọ́ mo ti kọ́ ilé janturu, fẹ́ ìyàwó mẹ́sàn àn , bí ọmọ 35 – Alfa to n ṣa irin ni atan
- Oloye Adeniji Ige, Mínísítà ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà dágbére fún ayé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún
- Ohun tí a mọ nípa ikọlù àwọn agbébọn sí ilé ìtura ní Ikorodu rèé
Tọkọtaya naa sọ pe o gbọdọ san ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹta din mẹwaa Dọla ($650,000) gẹgẹ bi owo itunu, ti ko ba fi bi ọmọ-ọmọ fun àwọn laarin ọdun kan.
Ọmọ wọn ati iyawo rẹ ko tii sọ ohunkóhun lori igbesẹ awọn òbí naa.
Àwọn òbí naa fi ẹ̀sùn ifiyajẹni kan ọmọ wọn, nitori pe ko mu inu wọn dun.
Ọgbẹni Prasad sọ pe ẹgbẹrun lọna marunlelọgọta Dọla, ni oun fi ran lọ sile ẹ̀kọ́ awakọ baalu nilẹ America lọdun 2006.
O pada si India lọdun 2007, ṣugbọn o padanu isẹ rẹ, to si jẹ pe o le ni ọdun meji, ti ẹbí rẹ fi n fi owo bo àṣírí rẹ.
Shrey Sagar, ẹni ọdun marundinlogoji, pada ri isẹ awakọ baalu.
Àwọn obi rẹ sọ pe awọn ni àwọn ba wa iyawo to fẹ, Shubhangi Sinha, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, lọdun 2016.
Iwe iroyin India Times, jabọ pe ireti awọn naa ni pe àwọn mejeeji yoo bi ọmọ-ọmọ ti awọn yoo ma a ba ṣeré, lasiko ifẹhinti àwọn.
Àwọn obi naa sọ pe ile itura olowo iyebíye ni àwọn sanwo rẹ lati ti ṣe ayẹyẹ igbeyawo wọn, wọn ra ọkọ awodami ẹnu ọkọ ayọkẹlẹ ($80,000) fun tọkọtaya, wọn si tun sanwo fun irinajo 'honeymoon' wọn nilẹ okeere.
- Ó dàbí ẹni pé ẹ kò mọ̀ ìdí tí mo fi ń díje dupò ààrẹ, òhun rè é - Tinubu ṣàlàyé
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Fífún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
Agbẹjọro tọkọtaya naa, AK Srivastava, sọ fun Iléeṣẹ́ iroyin The National, pe awọn onibaara oun beere fun owo itunu, nitori pe iwa ika ni ọmọ wọn ati iyawo rẹ hu si wọn, eyi to nipa ni 'ilera ọpọlọ' wọn.
"Gbogbo obi lo ma n foju sọ́nà lati ri ọmọ-ọmọ wọn. Wọn si ti n reti fun ọpọlọpọ ọdún."
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ni igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹsun naa, n'ilu Haridwar.
Iru ẹjọ ti awọn obi yii pe ọmọ wọn, ko waye ri ni orile-ede India.

















