Woman in politics: Iyabo Anisulowo: Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Ọrọ eto aabo Naijiria ti n dẹru ba ni pẹlu ijinigbe ati agbenipa- Iyabo Anisulowo.

Asofin Veronica Iyabo Anike Anisulowo gbalejo BBC Yoruba, o sọrọ ilẹ kun lori eto iṣẹlu Naijiria lasiko yii.

O mẹnuba iṣoro ifẹ owo ati ainifẹ ara ilu to gbode kan.

O sọ nipa sisọ pataki iriri, ọpọlọ pipe ati awọn amuyẹ nu nitori ifẹ owo ati agbara.

Kini Anisulowo sọ nipa ọdọ ati Obinrin?

Aṣofin Iyabo Anisulowo sọrọ nipa iṣoro to n koju ọdọ Naijiria ati awọn obinrin lasiko yii.

Bakan naa lo tọrọ aforijin lọwọ wọn.

O tun wa gba wọn nimọran lati tẹsiwaju nitori laipẹ ohun gbogbo yoo yipada.