Ìbádọ́gba nínú ìsèlú àti iṣẹ́ láwùjọ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsóké

Àkọlé fídíò, Ìbádọ́gba nínú ìsèlú àti iṣẹ́ láwùjọ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsóké

O ni ìdí ti Ọlọrun fi da àwọn obìnrin 'Obinrin jẹ amuludun'.

Ọsẹ yii ni ọsẹ ayajọ awọn obinrin ni gbogbo agbaye.

BBC Yoruba fi ọrọ wa takọtabo lẹnu wo lori pataki ibadọgba fun idagbasoke eyi to jẹ akori eto ti ọdun yii.

Opọ gba pé asiko ti to ki a faaye gba ibadọgba larin ọkunrin ati obinrin paapaa ninu oṣelu Naijiria ki idagbasoke le jẹ jade.

Bẹẹ, ọmọde gbọn, agba gbọn la fi da Ilẹ Ifẹ ni ọrọ naa, ohun ti ọkunrin ko le ri ṣe, o ṣeeṣe ti a ba fun obinrin laaye ko ṣe e ju ohun ti a lero lọ.

Iranlọwọ nla fun ọkọ ni obinrin jẹ lọọdẹ ọkunrin to ba mọ itọju aya.

Anfani pọ fun abo to ba ni itẹriba, ifẹ àti iwa tutu bii adaba ninu ile ati lawujọ.