2019 Nigeria Elections: INEC ní olùdíje leè yẹ̀bá fún ẹni tó bá wù ú

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Akala lè ṣàtìlẹ́yìn fẹ́ni tó bá wù ú

Nibayii ti eto idibo gomina lawọn ipinlẹ n kanlẹkun gbọngbọn, ọpọ awọn oludije latinu awọn ẹgbẹ oselu lorisirisi ni wọn ti n yẹba sẹyin, ti wọn si n se atilẹyin fun oludije kan ninu ẹgbẹ oselu miran.

Bẹẹ ba gbagbe, Adebayọ Alao Akala, ti ẹgbẹ oselu ADP nipinlẹ Ọyọ, ti yẹba bii oludije fun ẹgbẹ oselu naa, to si to sẹyin oludije fẹgbẹ oselu APC, Adebayọ Adelabu.

Bakan naa si lawọn oludije latinu ẹgbẹ oselu SDP, ZLP, NPM ati bẹẹ bẹẹ lọ to sẹyin oludije fẹgbẹ oselu PDP, Seyi Makinde.

Bakan naa si lọrọ sori lawọn ipinlẹ yoku bii Rivers, Kano, Kwara ati Eko.

Nigba to n dahun ibeere lori boya igbesẹ naa lee nipa lori eto idibo to n bọ, oṣiṣẹ alarina fun ajọ INEC nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Femi Akinbiyi sọ pe, niwọn igba ti ẹgbẹ oṣelu ko ba ti yi orukọ rẹ pada, awọn ọmọlẹyin rẹ le dibo fẹgbẹ to ba wu wọn.

Ọgbẹni Akinbiyi fikun ọrọ rẹ pe, tawọn ẹgbẹ oṣelu ba ko ara wọn jọ pọ lati jẹ ọkan, ni ọrọ kan ajọ INEC.

O ni wọn ni lati fi orukọ tuntun ti wọn fẹ jẹ ranṣẹ pẹlu awọn oloye tuntun ninu ẹgbẹ.

Adebayo Akala pẹlu Adebayo Adelabu
Àkọlé àwòrán, Idibo gomina ni ipinlẹ Oyo

Lori bi gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri Otunba Adebayo Alao-Akala to jẹ oludije si ipo gomina fẹgbẹ ADP tẹlẹ ṣe kede atilẹyin fun oludije APC Oloye Adebayo Adelabu Penkelemesi, o ni Akala lanfani labẹ ofin idibo lati ṣe bẹẹ.