Nigeria Elections 2019: Iléẹjọ́ ní Adebutu pẹ́ kó tó pe ẹjọ́ tako Kashamu

Buruji Kashamu

Oríṣun àwòrán, Buruji Kashamu

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abẹokuta tun ti fidi rẹ mulẹ pe sẹnetọ to n soju ẹkùn idibo Ila oorun ipinlẹ Ogun, Buruji Kashamu ni oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ile ẹjọ fagile ẹjọ ti ọmọ ẹgbẹ PDP, to tun jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ọladipupọ Adebutu pe, tako yiyan Kashamu gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ.

Adajọ Abubakar Shittu fidi rẹ mulẹ pe, olupẹjọ pẹ ko to o gbe ẹjọ naa wa sile ẹjọ, pẹlu alaye pe, ọjọ Kejila oṣu Kẹrin ọdun 2018 ni igbesẹ ẹgbẹ waye, ṣugbọn Adebutu ko pe ẹjọ titi di oṣu Kejila ọdun 2018.

Bakan naa lo sọ pe, ẹgbẹ oṣelu PDP tapa si aṣẹ ti ile ẹjọ pa fun wọn pe, wọn ko gbọdọ pe ẹjọ mi i lori ẹni to lẹtọ lati ṣeto idibo abẹle tabi fun ajọ eleto idibo ni orukọ awọn oludije ẹgbẹ.