BBCGovDebates: Kí lo mọ̀ nípa Kashamu tó fẹ́ jẹ gómìnà l'Ogun?

Kashamu kawe gboye ninu amojuto eto okooweo lati ile ẹkọ Pitman College, to wa ni ilu London.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kashamu kawe gboye ninu amojuto eto okooweo lati ile ẹkọ Pitman College, to wa ni ilu London.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun, ọdun 1958 ni wọn bi Buruji Kashamu nipinlẹ Ogun. O si n ṣoju ẹkun idibo ila oorun ipinlẹ Ogun nile aṣofin agba Naijiria.

O lọ si ileewe alakọbẹrẹ Ansarudeen nilu Ijẹbu Igbo. Bakan naa lo lọ si ileewe Igbobi College , ko to o di pe o kawe gba oye ninu amojuto okoowo ni Pitman College nilu London.

Àkọlé fídíò, 'Bukola Saraki ni adari wa' - Razaq Atunwa, Kwara

O jẹ ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Ogun.

Kashamu ni Sẹnetọ to n ṣoju ẹkùn idibo Ila Oorun Ogun nile aṣofin agba Naijiria.

Wọn le e kuro lẹgbẹ PDP lọdun 2018, sugbọn ile ẹjọ giga kan nilu Abuja pada wọgile igbesẹ ẹgbẹ.

Kashamu kawe gboye ninu amojuto eto okooweo lati ile ẹkọ Pitman College, to wa ni ilu London.

Iṣẹ kata-kara ni Kashamu n ṣe.

Lọdun 1998, wọn fi ofin mu Kashamu ni ilẹ Gẹẹsi fun awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu oogun oloro, lẹyin to gbiyanju lati wọ orilẹede naa pẹlu owo igba le ọgbọn ẹgbẹrun Dọla. Wọn si da a silẹ lọdun 2003.

Àkọlé fídíò, #BBCGovDebate: Olùdíje 5 ni yóò kópa nínú ìpàdé ìtagbangba l‘Ogun