Àwọn nnkan tó yẹ kí o mọ nípa Adekunle Akinlade ti ADM

Aworan Gomina Amosun Aarẹ Buhari ati Adekunle Akinlade

Oríṣun àwòrán, @AHMAD BASHIR

Àkọlé àwòrán, Aworan yi n kan awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan lominu

Bi eeyan ba gbiyanju lati kọ itan irinajo aṣoju Adekunle Akinlade ninu agbami oṣelu Naijiria o ṣeeṣe ki iwe kun.

Lootọ ni pe ko ju ọmọ odun mọkandinlaadọta lọ ṣugbọn lẹnu igba ti o gbe apoti ibo lati du ipo Gomina ni ipinlẹ Ogun, ọrọ ko sin lẹyin rẹ.

Àkọlé fídíò, #BBCGovDebate: Olùdíje 5 ni yóò kópa nínú ìpàdé ìtagbangba l‘Ogun

Fun awọn to ti n tẹle ọrọ rẹ bọ tipẹ, ko ni ya wọn lẹnu ti a ba ṣe apejuwe Adekunle Akinlade gẹgẹ bi oludije ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun yan laayo lati jẹ Gomina lẹyin rẹ.

Adekunle Akinlade, Aarẹ Buhari ati Gomina Amosun

Oríṣun àwòrán, oGUN STATE GOVERNMENT

Àkọlé àwòrán, Èdèàìyedè ti ń wáyé nípínlẹ̀ Ogùn láàárín Gómìnà Amosun àtàwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC lápapọ̀

Toun ti bi Gomina Amosun ṣe gbaruku ti i to, Adekunle padanu tikẹti ẹgbẹ oselu APC lẹyin ti igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ APC kede Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi aṣoju ẹgbẹ ninu idibo Gomina ọdun 2019.

Igbeṣẹ yii mu ki Adekunle fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ ti o si lọ gba tikẹti ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ Allied Peoples Movement, ADM.

Ohun to yẹ ki mọ nipa Adekunle

  • Ile ẹkọ girama Yewa High School ni Adekunle Abdulkabir Akinlade ti kawe jade
  • Lọdun 1995 lo kawe gboye ninu imọ oṣelu ni ile iwe giga fasiti ipinlẹ Eko, Lagos State University
  • Lọdun 2015,o dije ipo aṣoju fun ẹkun Egbado South ati Ipokia labẹ asia APC ti o si jawe olubori
  • Ṣaaju ki o to di aṣoju, o jẹ oluranlọwọ agba fun Gomina Amosun lori ọrọ owo ori ati pipawo wọ akoto ijọba

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Bọlanle Aliyu: N kò nílò bàbá ìsàlẹ̀ láti di gómìnà