APC Rally: Àdúgbò Festac ni ìjàmbá tó mú ẹ̀mí lọ ti wáyé

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mẹta ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọto waye nigba ti wọn n lọ sibi ipolongo idibo fun oludije fun ipo sẹnẹt fun ẹkun idibo iwọ oorun Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Solomon Olamilekan Adeola lọjọ Aje.
Ile iṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko, to fidi ọrọ naa mulẹ pẹlu BBC Yoruba ṣalaye pe, awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ko ti de ibi Ipolongo ti wọn n lọ lagbegbe Festac, ti iṣẹlẹ naa fi ṣẹlẹ.
Agbẹnusọ fun ile iṣe ọlọpaa ipinlẹ Eko fikun ọrọ rẹ pe, ọpọ eeyan lo fara pa ninu ijamba ọkọ.
O ni awakọ naa ko le dari ọkọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC wa ninu rẹ mọ, lẹyin naa ni ọkọ yii gbokiti.
Eleyi yatọ si awọn iroyin kan to lu ori ayelujara pa pe ẹmi awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan bọ nibi ipolongo idibo.
Agbegbe Festac ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.









