#BBCRepDebate: Ìjíròrò náà fáwọn olùdìbò l‘Eko ní ànfàni láti bèèrè ohun tó jẹ wọ́n lógún

Obanikoro, Wellington, Owolabi, bakare àti Adimefe
Àkọlé àwòrán, Awon oludije Ile igbimọ asoju sofin Eti Osa

Onírúurú ìlérí ní àwọn tó ń dije dupò nílè ìgbìmọ̀ aṣojú sòfin fún ẹkun Eti Osa ti ṣe fún àwọn olùdibò níbi ìpàdè ìtagbangba tí BBC sagbátẹrù rẹ̀ pẹ̀lú ìfọwọ́sowọpọ̀ Media Room Hub àti Pulse Nigeria.

Awọn oludíje márùn-ún tó péju síbẹ̀ ní Olubankole Wellington (Banky W) láti ẹgbẹ́ òṣèlú Modern Democratic Party (MDP).

BANKOLE WELLINGTON
Àkọlé àwòrán, #BBCRepDebate: Ìjíròrò náà fáwọn olùdìbò l'Eko ní ànfàni láti bèèrè ohun tó jẹ wọ́n lógún

Awọn yoku ni Ibrahim Obanikoro lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ All Progressives Party (APC), Tessy Owolabi tí ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party (SDP) ati Omotesho Tony Bakare ti People's Democratic Party.

FERDINAD ADIMEFE
Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ ẹkún omi Eti Ọsa ló jẹwa lógun - Àwọn olùdíje aṣojú-sòfin

Bakan naa ni Ferdinand Ladi Adimefe tí ẹgbẹ òṣèlú Alliance for New Nigeria (ANN) ko gbẹyin nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú ìfọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ tó wáye fún bii wákàti méji, gbogbo àwọn olùdíje ló sàlaàyé pé, ohun tó jẹ àwọn lógun jùlọ ní láti móju tó ọrọ̀ ẹ̀kún omíyale àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tó ń da àwọn ènìyàn etí ọsà láàmú láti ọjọ́ pípẹ́ wá.

TESSY OWOLABI
Àkọlé àwòrán, Adimefe ti ẹgbẹ́ òṣèlú ANN sàlàyé pé òhun yóò kọ́kọ́ ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀ná táwọn ọ̀dọ̀ yóò gbà ni ìmọ̀, lẹ́yìn èyí ni wọn yóò wá pèsè irinṣẹ́ ti wọn yoo lọ.

Bakan náà, lori ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́, Adimefe ti ẹgbẹ́ òṣèlú ANN sàlàyé pé, òun yóò kọ́kọ́ ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀ná táwọn ọ̀dọ̀ yóò gbà ni ìmọ̀ lẹ́yìn èyí ni wọn yóò wá pèsè irinṣẹ́ ti wọn yoo lo.

IBRAHIM OBANIKORO
Àkọlé àwòrán, #BBCRepDebate: Ìjíròrò náà fáwọn olùdìbò l'Eko ní ànfàni láti bèèrè ohun tó jẹ wọ́n lógún
Àkọlé fídíò, 'A ni òfin púpọ̀ ní Naijiria ṣùgbọ́n a kò bọ́wọ́ fún un ni'

Ní ti Obanikoro, ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ó ni ohun tó ṣe patàkì jùlọ ni láti tẹti sílẹ̀ fún ohun ti àwọn ènìyàn fẹ, èyí ni yóò sọ ohun ti àwọn yóò ṣe, tí ètò amúludùn kò sì ni wọn ni agbegbe Eti Osa.

OMOTESHO BAKARE
Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ ẹkún omi Eti Ọsa ló jẹwa lógun - Àwọn olùdíje aṣojú-sòfin

Ogbẹni Bakare ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ó ṣe pàtàkì láti jẹ aṣojú tòótọ, èyí ni yóò fún àwọn ènìyàn àti láti le dúna dúrà pẹ̀lú wọn.

Ètò ijiroro náà fún àwọn olùdìbò ní ànfàni láti bèèrè ohun to jẹ wọn logun lọ́wọ́ awọn oludije to n gbero lati lọ soju wọn nile asoju-sofin ilẹ wa.