Àwọn nkan tó ṣe kókó nípa olùdíje gómìnà ADP l'Ogun, Dimeji Bankọle

Dimeji Bankọle

Oríṣun àwòrán, dimeji bankole/facebook

Ninu awọn ọdọ orileede Naijiria to ti di ipo to lamilaka mu nijọba ni Dimeji Bankole wa-ọmọ ọdun mẹtadinlogoji lo jẹ nigba ti o di ọmọ ile asojusofin.

Saaju ki o to di olori ile asojusofin labuja pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria ni ko fẹrẹ gbọ orukọ rẹ ri.

Wọn bi Sabur Ọladimeji Bankọle ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla ọdun 1969 nilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun.

O kẹkọ nileewe Baptist Boys'High School lati ọdun 1979;

  • Albany College nilu London lọdun 1985;;
  • University of Reading nilẹ Gẹẹsi lọdun 1989
  • University of Oxford nilẹ Gẹẹsi lọdun 1991;
  • Ati Harvard University nilẹ Amẹrika lọdun 2005.

Lọdun 2002, wọn dibo yan Bankọle sile igbimọ aṣojuṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, lati ṣoju ẹkun idibo Gusu Abẹokuta nipinlẹ Ogun.

Lasiko to fi wa nile aṣojusofin, o jẹ Igbakeji Alaga igbimọ to n mojuto eto ẹnawo. Wọn pada dibo yan Bankọle lọdun 2007.

Ninu oṣu Kẹsan ọdun 2007, igbimọ kan nile aṣofin naa ṣewadi Olori ile nigba naa, Patricia Etteh fun nina ọpọlọpọ owo lati fi tun ile rẹ ṣe , ati fi ra ọkọ ayọkẹlẹ. Ọrọ naa pada yọri si ki Etteh kọwe fipo silẹ ninu oṣu Kẹwa.

Lọjọ kini, oṣu Kọkanla, wọn dibo yan Bankọle nile aṣofin lati rọpo Etteh. Eyi to sọ ọ di Olori ile aṣojusofin to kere julọ ni ọjọ ori. Ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni lasiko naa.

Oun si ni Olori ile aṣojuṣofin kẹsan ni Naijiria.

Asiko Dimeji Bankole lati ri awọn igbesẹ kọọkan nile asofin to fi mọ bi wọn ti ṣe paṣẹ lọrọọkun nile fun awọn ọmọ ile asofin to ko si ija ninu ile,bibuwọlu aba to fi aye gba iwadi lori ohun ti ijọba tabi ẹka rẹ ba n ṣe,Freedom of Information Bill ati bẹbẹ lọ.

Saa kan pere lo ṣe nile asofin ti ọrọ biliọnu mẹwa ẹyawo owo fun awọn asofin si jẹ epo ti o ta si asọ aala rẹ.

Amọ sa,lati igba ti o ti kuro lori oye ni o ti pada sile ti ko sifi taratara da si ọrọ oṣelu bi kii ṣe igba ti o gbapoti ibo lati du ipo Gomina nipinlẹ Ogun.

Oun ni oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Action Democratic Party, ADP nipinlẹ Ogun.