Nigeria Elections 2019: Àwa Mọ́gàjí ilẹ̀ Ibadan kìí dásí ọ̀rọ̀ òṣèlú'

Gbangan Mapo
Àkọlé àwòrán, Ipade itagbangba BBC Yoruba

Lọjọbọ ni iroyin kan jade lori ẹrọ ayelujara pe, awọn Mọgaji ilẹ Ibadan ti kilọ fun eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Tinubu, lati mase da si ọrọ oṣelu ipinlẹ Ọyọ.

Iroyin naa to ni awọn igbimọ Mọgaji ilẹ Ibadan sọ, lo tun n fewe ọmọ mọ gomina nigba kan nipinlẹ Ọyọ, Alao Akala leti pe, ko sọ ohun ti yoo maa sọ nipa Osi Olubadan, Rashidi Ladọja.

Ṣugbọn ṣaa, ọkan lara awọn Mọgaji ilẹ Ibadan, Oloye Waheed Yusuf Fadairo, tii se Mọgaji ile Ado ni Oke-Ado, Ibadan sọ fun BBC Yoruba pe, awọn kan to ṣẹṣẹ jẹ oye Mọgaji, ti ko ju bi mẹta lọ, lo maa n sọ iru awọn ọrọ bẹẹ.

O ni awọn Mọgaji to wa ni igun Olubadan kii ba wọn dasi tabi sọ iru ọrọ bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa

Lori iha ti wọn kọ si eto idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọyọ, Fadairo sọ pe, awọn mọgaji kii dasi ọrọ oṣelu, nitori pe ẹni ti awọn araalu ba ba lọ, naa ni awọn fọwọsi.

''Ẹni to ba si jawe olubori naa lo jawe olubori.''

Lori eto aabo lagboole ẹnikọọkan wọn lasiko idibo, o salaye pe, awọn gẹgẹ bi Mọgaji ti sọ fun awọn to wa ni agboole kọọkan, lati mojuto adugbo wọn, ati pe, ki wọ̀n mase bo aṣiri ọmọ to ba n hu iwakiwa.

O ni ki wọn o fi awọn isẹlẹ to ba waye ni sakani wọn to awọn alaṣẹ agboole leti, lati le jẹ ki awọn ọlọpaa mọ si.

Ọdọkunrin kan padanu ẹmi rẹ sọwọ awọn janduku ni agbegbe Kudẹti niluu Ibadan, lasiko idibo aarẹ to waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Keji.