2019 Election: Akala ní aráàlú kò ní kábàámọ̀ tí Adelabu bá wọlé

Otunba Christopher Adebayo Alao-Akala ati loye Adebayo Adelabu Penkelemesi
Àkọlé àwòrán, Idibo gomina ipinlẹ Oyo

Bi idibo gomina se wọ le de, gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Otunba Adebayo Alao-Akala ti kede pe oludije labẹ asia ẹgbẹ APC, Oloye Adebayo Adelabu yoo sọ ipinlẹ Oyo ji to ba wọle gẹgẹ bi gomina.

Akala fọrọ yii lede nibi ipolongo idibo fun oludije APC niluu Ogbomoso ni Ọjọru.

Akala rọ awọn eeyan ilu Ogbomọṣọ lati tu yaya jade dibo fun Adelabu Penkelemesi lọjọ Abamẹta.

Àkọlé fídíò, Nigeria Elections 2019:Ìbò la ní kí ẹ dì, àwa kò bá tìjà wá

O ni wọn ko ni kabamọ ti wọn ba dibo yan Adelabu gẹgẹ bi gomina tuntun nipinlẹ Oyo.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn oludije fẹgbẹ oṣelu ADC, Sẹnẹtọ Olufemi Lanlehin, ZLP, Oloye Sharafadeen Alli. SDP, Oloye Bolaji Ayorinde ati oludije fẹgbẹ oṣelu NPM, Edward Ladoye naa ti gba lati ṣatilẹyin fun oludije fẹgbẹ oselu PDP, Seyi Makinde, ninu idibo ọjọ Abamẹta.