Slain Ekiti Police woman: Ìyá rẹ̀ ní àìrìṣẹ́ṣe ló mú kí Bukola Olawoye gba iṣẹ́ ọlọ́pàá

Àkọlé fídíò, Slain Ekiti Police woman: Ìyá rẹ̀ ní àìrìṣẹ́ṣe ló mú kí Bukola Olawoye gba iṣẹ́ ọlọ́pàá

Adura ti ẹda kọọkan maa n gba ni pe ohun ta jẹ la n wa, ka ma pade ohun ti yoo jẹ wa.

Amọ adura yii ko gba rara fun obinrin ọlọpaa kan nipinlẹ Ekiti to lọ sẹnu isẹ lọjọ ti wọn n se atundi ibo sile asoju sofin ilẹ wa.

Obinrin ọlọpaa naa, Sajẹnti Bukola Olawoye lo bawọn sisẹ agbofinro lọjọ Satide, Ogunjọ osu Kẹta ọdun 2021 nibi atundi ibo ẹkun Ila oorun Ekiti sile asoju sofin.

Bukola ni ọta ibọn ba lasiko ti rogbodiyan gbode nibi atundi ibo naa, to si jade laye lọjọ Keji nile iwosan to ti n gba itọju, eyi to mu ki wọn so eto idibo naa rọ.

BBC Yoruba fẹsẹ kan de ile oloogbe Olawoye, lati mọ bi adanu obinrin ọlọpaa naa se ri lara wọn.

Nigba ti wọn n ba wa sọrọ, iya ati alagbatọ obinrin naa ni airisẹse lo mu ki Bukola lọ gba isẹ ọlọpaa, ti oun si ri iran iku rẹ ni kete ti wọn yinbọn mọ.

Wọn wa n bẹ ijọba lati se awari ẹni to yinbọn mọ obinrin naa, tii se ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, to si fi ọmọ meji silẹ saye lọ.

Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Ekiti naa ni oun ri isẹlẹ naa bii eyi to wu Ọlọrun nitori gbogbo eto to yẹ ni awọn se lati dena rogbodiyan lasiko ibo naa.