Saki Iron pot: Kò sí agbo ilé tẹ́ẹ dé ní Saki tẹ́ ò ní bá oníṣẹ́ kòkò àmọ àwọn ọmọ wa ń sá
"1973 ni mo bẹrẹ iṣẹ, awọn taa jọ bẹrẹ ko sẹni to n ṣiṣẹ mọ".
Oloye Baba Ewe Mathew Ogunrinde ba BBC Yoruba sọrọ nipa aṣiri to wa nidi bi koko Saki ṣe jẹ eyi to dara ju kaakiri.
"Ko si agbo ile ti o de ni Saki tẹ o ni ba onikoko irin".
O ni iṣẹ to le ni iṣẹ amokoko, “ti eeyan ko ba mu ọkan daadaa, yoo sa nibẹ”.
- Rògbòdìyàn míì bẹ́ sílẹ̀ láàrin Yorùbá àti Bòròró ní Saki, ẹ̀mí bọ́, dúkìá ṣòfò
- Èèmọ̀! Saka dáná sun 'ààlè' rẹ̀ tọmọ-tọmọ n'Ibadan, òun nàá tún jóná kú
- Wo àwọn Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá tó ti jẹ́ látọdún 1999
- Àwọn ajínigbé bèèrè fún óúnjẹ àti suya kí wọ́n tó tú ọkọ, ìyàwó àtàwọn ọmọ sílẹ̀ l'Ondo
- Bí Oladeinde Fernandez tí bàbá rẹ̀ kò gbajúmọ̀ ṣe rìn ín tó ń wọ́ ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ owó lókè òkun
- Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ nílé Wasiu Alabi Pasuma, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń relé ọkọ
"Tori ati ṣe koko irin, béèyàn ó ṣe máa fara yá iná nìyìí".
Ẹwẹ, Baba Ewe ni anfani toun ti jẹ ninu iṣẹ amọkoko yii kii ṣe kekere.
"Mo kọlé, àwọn ọmọ mi lọ ileewe wọn d ṣaṣeyọri. Mo ni ọmọ to ti di nọọsì, oṣìṣẹ láàbù, wolé wolé".
Arabinrin Emily ṣalaye itan koko yii pe "ọmọ ilu Saki to lọ si Togo ló mú sámpù koko irin wá tí a fi gbajúmọ báyìí".
Àṣírí kòkò irin Saki: Iyẹpẹ wa ló bá ìrú àwọn kòkò irin yìí mu
Baba Ewe ni ṣe ni awọn ọmọ awọn to n ṣe iṣẹ yii kaakiri ilu mii lo mọ aṣiri ọrọ iyẹpẹ yii.
O ni iyẹpẹ to wa nibomii le dara o “amọ ti Saki yatọ".
"Amala, Jollof Rice, kódà òhun ni wọn fi ń rí poundo yam rò nilu oyinbo bi wn ba fẹ ṣenawo laarin awọn ara ilẹ adulawo".
Baba Ewe ni bí Koko ìrin wọn ṣe n sìnkú àgbà, ṣèyàwó àti ọpọ ayẹyẹ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.
"Mi ò fẹ káwọn ọmọ jogúnbá iṣẹ tí mò ń ṣee yí àfi ọkan lára wọn to si ti mọ ọ doju ami".
Awọn amọkoko Saki ke si ijba fun iranwọ̀ fun Aluminium eyi to jẹ́ ohun elo ti wọn nilo ju fun iṣẹ ti kii dibajẹ.

