BBC 100 Women Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ elétò ìlera ló ti n lo tọ̀nà ìgbàlódé láti fiṣe àkọsílẹ̀
Millicent Nyawade Ochieng jẹ obinrin kan to n ṣiṣẹ ilera ọfẹ ni agbegbe rẹ ni Kenya.
O maa n lọ kaakiri igberiko láti ṣabẹwo sawọn alaboyun àti láti fawọn ọmọ wẹwẹ labẹrẹ ajẹsara.
Ni ilẹ Adulawọ tẹlẹ, ọpọ igba lawọn eeyan maa n ṣe nkan lọna atijọ ṣugbon bayii, imọ igbalode ti n mu iyipada ba eto ilera awọn eniyan.
O maa n lọ sawọn igberiko lati ṣabẹwo si awọn alaboyun ati lati fun awọn ọmọ ọwọ́ labẹrẹ ajẹsara.
Millicent sọrọ lori bo ṣe maa n fi gege kọ akọsilẹ ilera awọn ara igberiko rẹ silẹ tẹlẹ ki o to di pe o n lo ẹrọ igbalode ti Medic Mobile.
Opolopo awọn oṣiṣẹ eleto ilera lo n lo ẹrọ igbalode Medic Mobile ni orilẹ ede mẹẹdọgbọn nilẹ Adulawọ bayii.
Ọpọ́n ìmọ̀ ti sun siwaju ni eyi to ti jẹ iṣẹ eto ilera nigberiko rọrun sii.
Erọ yii n sọ ọna abayọ fawọn aisan bii ibà, bakan naa lo ti di kari ile fawọn eleto ilera ni Kenya nitori iwulo rẹ pọ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alaboyun gan an lo n forukọ silẹ nipa ẹrọ yii ni kete ti wọn ba ti loyun ni Kenya.
#BBC100women