ASUU Strike: Bí àwọn kan se dunnú, làwọn kan fajúro

Àkọlé fídíò, ASUU Strike: Bí àwọn kan se dunnú, làwọn kan fajúro

Abẹwo BBC Yoruba sinu ọgba fasiti Ibadan fi han pe, bi iyansẹlodi awọn olukọ ninu ọgba naa se mu ẹrin ba awọn eeyan kan, lo ko ironu ojiji ba awọn miran.

Nigba ti awọn kan ni inu awọn dun pe ASUU n mọ isẹ loju, awọn miran ni idaduro ni eyi yoo jẹ lati tẹsiwaju feto ẹkọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan to ba wa sọrọ ni, yoo dara ki ijọba apapọ tete pese ohun ti ASUU n fẹ fun wọn, nitori iyansẹlodi ASUU yii ti di ọdọọdun.

Koda, awọn ontaja ninu ọgba fasiti naa ni ebi, gbese ati keresi elebi ni iyansẹlodi ASUU naa ba de fun awọn ti ijọba ko ba tete da awọn olukọ fasiti to n wo isẹ niran lohun.