Minimum wage: Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka isẹ́ ajé tó se kókó ló fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ìyansẹ́lódì náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi iroyin ṣe n kaakiri lori iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ, eleyii ti o ṣeeṣe ki o bẹrẹ ni ọjọ kẹfa oṣu kọkanla ọdun 2018, ọpọ lo ti wa ninu ipaya ati iwariri bayii lori ipa ti irufẹ iyanṣẹlodi bẹẹ lee ko ba eto ọrọ aje orilẹede Naijiria.
Ni lọwọlọwọ ti a n sọrọ yii, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ẹka ọrọ aje ti o ṣe koko gbogbo, ni wọn ti n faramọ gigun le iyanṣẹlodi yii.
Amọṣa, bi ọrọ ti ṣe ri yii, o yẹ ki awọn ọmọ orilẹede yii gbaradi fun ohun yowu to lee waye pẹlu iyanṣẹlodi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni iwọn igba ti o jẹ wi pe, ọlọjọ gbọọrọ ni iyanṣẹlodi yii, gẹgẹ bii awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ṣe sọ.
Eyii ni awọn ohun marun ti o gbọdọ ṣe ni igbaradi fun iyanṣẹlodi yii:
Epo Bẹntirolu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko si idaniloju pe ipese epo bẹntiroolu ko ni fi ara gba ninu iyanṣẹlodi yii, to ba n pẹ ju boṣe lọ. Ohun ti iroyin n sọ ni pe, o ṣeeṣe ki awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ agbepo rọbi lorilẹede Naijiria, NUPENG pẹlu darapọ mọ iyanṣẹlodi yii.
Mura silẹ fun ipese ina.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lootọ awọn ẹka ipese ina ọba ti di aladani bayii, ọrọ idasilẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ nibẹ ko si tii duro daadaa nitorinaa o ṣeeṣe ki awọn oṣiṣẹ nibẹ ma gunle iyanṣẹlodi.
Amọṣa, ko yẹ ki a gbagbe pe afẹfẹ gaasi ni awọn ileeṣẹ ti o n pese ina ọba n lo, bi awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹka afẹfẹ gaasi yii ba yanṣẹ lodi, o di dandan ki ipese ina o fara gba.
Bi o ba ri bẹẹ, ki a gbaradi fun ọna ipese ina miran, yala ti ohun elo amu oorun ṣ'agbara ina solar, tabi ẹrọ amunawa generator, abi atupa.
Ohun elo ounjẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nitori iṣoro irinkerindo ọkọ ti o lee waye, eleyi ti o lee ṣe idiwọ lilọ si ọja lọ ra awọn ohun jijẹ ati idana gbogbo, yoo dara ki a ra awọn ohun elo jijẹ ati ile gbogbo bii elo ọbẹ, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Afẹfẹ idana gaasi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Afẹfẹ idana gaasi ni ọpọlọpọ ile fi nṣe idana bayii, bi awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ afẹfẹ gaasi ba si darapọ mọ iyanṣẹlodi yii, afaimọ ki afẹfẹ idana gaasi o maa di afẹti.
Mojuto ọrọ aabo iwọ ati idile rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ju gbogbo rẹ lọ, ẹ mojuto ọrọ aabo ẹyin ati ẹbi yin nitori lasiko iyanṣẹlodi yii, o ṣeeṣe ki iwọde waye, asiko yii si ni oniruuru awọn eeyan n farahan ti erongba wọn yatọ si ti awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ to n ṣe aayan iwọde naa.













