Azeez Ismail: Ẹ wo Alfa Azeez Ismail tó ń sa irin ní àtàn tó fi kọ́ ilé janturu, fẹ́ ìyàwó mẹ́sàn àn, ọmọ 35

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Arakunrin Azeez Ismail ti gbogbo eniyan ni agbegbe rẹ n pe ni Alfa jakujaku ti sọ irinajo rẹ bi o ṣe di ọlọla ni idi ṣiṣa irin ni atan.
Bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ idọti ni awọn eniyan ka ṣiṣa ilẹ si ni atan, ti awọn miran tilẹ ma n pe wọn ni were tabi ajinigbe, iroyin ayọ ni Alfa jakujaku mu wa fun awọn eniyan yii.
Arakunmi Ismail to jẹ ẹni aadọta ọdun ni ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti bi oun, ti baba oun si jẹ ilumọọka ni ilu Ọyọ mẹrin iyawo mẹrin ati ọpọlọpọ ọmọ.
Azeez ni oun ko lọ si ileewe rara nitori awọn obi oun jẹ ki oun mọ wi pe oun fun ara oun lo kọjalẹ pe oun ko ni lọ si ileewe alakọbẹrẹ, amọ ile Keu ni oun fẹ lọ.
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Fí fún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
Bawo ni o ṣe bẹrẹ iṣẹ ṣiṣa irin ni atan?
''Lẹyin ti mo ka Keu, ti mo si da Alfa, ti mo da ile Keu temi silẹ, ni mo ro wi pe kini mo le ṣe, ni mo ṣe lọ si ariwa Naijiria.''
''Nigba ti mo de ibẹ lẹyin ọdun meji ti ko si nkankan, ni mo pada si ilu Ọyọ lati lọ yọju wo awọn obi mi.''
''Iya mi ni oun ti wo akọsejaye mi pe wọn ni lati ileto kan si omiran ni ma a ma lọ kaakiri, to si gba mi ni imọran lati lo jina rere lati wa iṣẹ ṣe nibẹ.''
''Lasiko ti mo n ro nkan ti mo le ṣe ni mo pade awọn eniyan to n sa irin ni atan,ti mo si ṣewadii lori bi wọn ṣe n ṣe iṣẹ naa.''
''Wọn ṣalaye pe awọn Hausa ni wọn ma n ta irin naa fun, eleyii lo mu mi darapọ mọ wọn.''
Alfa Azeez fikun pe awọn obi oun tabuku iṣẹ naa lẹyin ọsẹ meji ti oun bẹrẹ, pe awọn ọmọ orukan ti ko ri eniyan tọju wọn lo n ṣe iru iṣẹ bẹẹ amọ mọ kuro ni agbegbe naa lọ si Iṣẹyin ti mo si bẹrẹ diẹdiẹ.
''Alfa Jakujaku ni awọn eniyan ma n pe mi nitori iṣẹ atan ti mo n ṣe''
Arakunrin Azeez ni ọgbẹ ọkan ni o ma n jẹ fun oun ti awọn eniyan ba pe oun ni Alfa jakujaku, amọ iṣẹ ti oun ṣe lo jẹ ki oun fi ara daa.
Azeez ni opolopo eniyan lo ti pe oun ni were, ole ati ajinigbe nitori bi oun ṣe ri, ti oun si n gbe apo kọ ọrun.
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
''Wọn ti gba ọkọ ti mo fi n ṣiṣẹ ri nitori wọn ro wi pe ole ni mo wa ja ni agbegbe naa, ti wọn si fi iya jẹ mi.''
''Koda ọpọlọpọ igba ni wọn ti na mi, ti ọpọlọpọ obinrin si ti koro oju si ẹnu ifẹ ti mo ba kọ si wọn.''
''Mo ti di ọlọla, onilẹ ati ọpọlọpọ aṣeyọri ni idi iṣẹ atan ṣiṣa''
Azeez ni idi iṣẹ yii ni oun ti di onile ati ọlọla ni ọpọlọpọ.
O ni iyawo mẹsan an ni oun ti fẹ ti oun si kọ ile fun awọn iyawo oun yatọ si ile ara ti oun.
Bakan naa lo ni oun ni ọkọ yanturu ti oun si ti bi ọmọ marundinlogoji.
Azeez fikun un pe awọn ọmọ oun to ti dagba naa ti bẹrẹ si ni ṣe iru iṣẹ naa nitori naa inu oun dun lati fi iṣẹ naa le ọmọ lọwọ.
















