Ministers who has resigned: Ṣé lóòtọ́ ni Malami náà ti yí ọ̀kan rẹ̀ padà lórí ìkọ̀wéfipòsílẹ́ rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Others
Ngige yi ọkan rẹ pada, o peyinda pe oun ko dije dupo aarẹ Naijriia mọ́
Leyin ti ọpọlọpọ awọn adari ni Naijiria bẹrẹ si ni gba fọọmu lati dije dupo iṣẹlu ni ero awọn eeyan ti ṣotoọtọ.
Saaju lọjọ Eti ni aarẹ Buhari to n tukọ Naijiria ti ri iran ṣaaju gbogbo ikede awọn minista ati osise rẹKìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
Buhari kede pe enikẹni to ba fẹ dije dupo oṣelu ko kọwe fipo silẹ.
Leyin naa ni awon minista kan si kede ikọwefiposilẹ wonNgige kọrin tuntun mi ò díje dupò aàrẹ Nàìjíríà mọ́, mo ti padà sí ọ́ọ́fíìsì mínístá tí mo wà tẹ́lẹ̀
Dokita Chris Ngige wa lara a\won to fẹ dije dupo aarẹ..
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Ngige kọrin tuntun mi ò díje dupò aàrẹ Nàìjíríà mọ́, mo ti padà sí ọ́ọ́fíìsì mínístá tí mo wà tẹ́lẹ̀
Nibo ni ọrọ Chris Ngige de duro bayii?
Minista fun ọrọ iṣẹ ati ọrọ awọn osiṣẹ ni Naijiria, Chris Ngige ti kede pe oun yi ọkan oun pada.
O ni oun ko dije dupo aarẹ Naijiria mọ lọdun 2023.
Ṣaaju lo kede ipinnu rẹ lati dije dupo aarẹ fun awọn alatileyin rẹ ni ọjọ kokandinlogun, oṣu kẹrin ni ilu rẹ ni ijọba ibilẹ Idemili South ni ipinlẹ Anambra ni guusu ila oorun Naijiria.
Lọjọ Eti lo fi atẹjade sita nilu Abuja nibi eto isin idagbere ti aarẹ Buhari ṣe fun gbogbo awọn to n lọ ninu wọn nile ijoba ni Abuja.
- Orí ìpìlẹ̀ àṣeyọrí Buhari ni máa mọ lé tí mo bá fi di Ààrẹ - Fayemi
- Àsìkò ti tó kí ìjọba fihàn pé kò sẹ́ni tó kọjá òfin lórí ikú Deborah- Ẹgbẹ́ Mususlumi ní Nàìjíríà
- Ṣé lóòótọ́ ní pé arábìnrin tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá tí pàdánù ẹ̀mí rẹ̀?
- Ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV ṣe àkọsílẹ̀ bí àwọn ọmọ ogun Russia ṣe pa aráàlú méjì ní Ukraine
- Ilé tí mo kọ́ ni Ìlànà Omo Oòduà, mi ò lè sá kúrò níbẹ̀ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Ó dàbí ẹni pé ẹ kò mọ̀ ìdí tí mo fi ń díje dupò ààrẹ, òhun rè é - Tinubu ṣàlàyé
- Ìpàdé ìjọba Nàìjíríààti ASUU lórí ìyanṣẹ́lódì tún forí ṣánpọ́n
Bẹ́ẹ̀, naa ni iroyin mii tun jade pe Malami Abubakar to n dari eto idajọ Naijiria naa ti yi oun pada pe oun ko ṣe mọ.
Iroyin naa n sọ pe aarẹ Buhari lo rọ Malami lati maṣe dije dupo gomina to fẹ lọ fun ni ipinlẹ Kebbi.
Sugbon BBc ko tii fi eyi mulẹ pe lootọ ni tabi iroyin ofege titi di asiko yii ti a n ko iroyin yii jọ.

Oríṣun àwòrán, Presidency nigeria
Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari lórí ìdíje dupò òṣèlú lọ́dún
Lọjọru ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari paṣẹ pe ẹni kan kii jẹ meji laba Alade.
O noi pe gbogbo awọn ọmọ igbimọ iṣejọba rẹ to n gbero lati dije fun ipo oṣelu kan tabi omiran lati kọwe fi ipo gbogbo ti wọn di mu ninu igbimọ iṣakoso ijọba lorilẹede Naijiria silẹ bayii.
Minisita feto iroyin Lai Mohammed to kede aṣẹ naa lẹyin ti wọn pari ipade igbimọ alaṣẹ Niajiria to waye nile ijọba nilu Abuja ni awọn minisita naa ni di ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun oṣu karun un ọdun 2022 lati ṣe bẹẹ.
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- PDP wọ́gilé ìlànà jẹ kí n jẹ 'zoning' fún yíyan olùdíje ipò ààrẹ
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly ní Nàìjíríà , ASUP bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì, wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
Lati lee tubọ jẹ ki gbogbo awọn ti ọrọ kan bii minisita fun ọrọ oṣiṣẹ ati ijafafa iṣẹ, Dokita Chris Ngige to ni oun ṣi tun fẹ gbọ ero aarẹ na ki oun to kọwe fipo silẹ o le mọ pe ko si ere lọrọ naa.
Akọwe ijọba apapọ, Boss Mustapha ti fi iwe atẹjade ijọba kan sita lori ọrọ yii.
Ninu atẹjade naa, Boss Mustapha ni aṣẹ Aarẹ Buhari yii ko yọ awọn olori ati ọmọ igbimọ iṣakoso ileeṣẹ ati ajọ ijọba, aṣoju ijọba Naijiria nilẹ okeere, atawọn eeyan miran ti wọn yan sipo oṣelu silẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/APC United Kingdom
Atẹjade naa ni ki awọn minisita tọrọ kan lati fa iṣakoso le awọn akọwe agba ni ileeṣẹ ijọba ti wọn n dari lọwọ.
Awọn aṣoju ijọba loke okun yoo fa aṣẹ akoso le awọn igbake adari ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria lorilẹede ti ọkọọkan wọn ti n ṣiṣẹ.
Lẹyin ti aarẹ ti paṣẹ yii, eyi lawọn minisita to ti kọwe fi ipo silẹ:

Oríṣun àwòrán, Twitter/APC United Kingdom
Rotimi Amaechi, minisita fun igbokegbodo ọkọ
Gọmina ana ni ipinlẹ Rivers naa darapọ mọ idije lati dupo Aarẹ ọdun 2023 labẹ ẹgbẹ ọselu APC.
Amaechi lo jẹ gọmina fun ọdun mẹjọ ni ipinlẹ Rivers ki o to di Minisita fun iriina lati ọdun 2015.
Ṣaaju eyi lo ti kọkọ jẹ adari ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers.
Oju opo twitter APC nilẹ Gẹẹsi ni wọn ti kọkọ kede ikọwwefiposilẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, other
Ogbonnaya Onu, Minisiti fun imọ ẹrọ ati sayẹnsi
Ogbonnaya Onu jẹ gomina akọkọ ijọba awaarawa fun ipinlẹ Abia ko to di Minisita fun imọ ẹrọ ati sayẹnsi.
Ni ọjọ kẹfa oṣu karun un ọdun 2022 ni Ogbonaya Onu lọ ra fọọmu idije rẹ fun ọgọrun miliọnu naira.
Godswill Akpabio, minisita fọrọ agbegbe ẹkun Naiger Delta.
Godswill Akpabio di minisita lẹyin to jẹ gomina fun saa meji ni ipinlẹ Akwa Ibom labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ko to di igba ati agbọn rẹ gba ẹgbẹ oṣelu APC lọ lẹyin to padani idibo si ile aṣofin agba.
Lara awọn ohun ti ọpọ yoo ranti ni saa rẹ nipo ni wahala to gba ajọ idagbasoke awọn ipinlẹ to n wa epo rọbi ni Naijiria, NDDC.

Oríṣun àwòrán, other
Amugbalẹgbẹ fun un lori ọrọ iroyin, Jackson Udom ṣalaye fawọn akọroyin pe lootọ ni ọga oun ti kọwe fipo silẹ.
Iwe rẹ si ti tẹ akọwe ijọba apapọ orilẹede Naijiria, Boss Mustapha lọwọ.
Emeka Nwajiuba, minisita keji fun eto ẹkọ
Emeka Nwajiuba, minisita keji fun eto ẹkọ lo kọkọ kọwe fi ipo rẹ silẹ ninu gbogbo awọn minisita Aarẹ Buhari to fẹ dije fun ipo oṣelu kan tabi omiran.
Koda o ti gbe igbesẹ naa ki aarẹ to kede aṣẹ rẹ, eleyi to mu ki Aarẹ Muhammadu Buhari kan sara sii fun ẹmi lamẹtọ to ni to si ni ireti oun ni pe gbogbo awọn iyoku rẹ yoo gbe igbesi bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, other
Ọrọ ikọwefiposilẹ gbogbo awọn to n gbero ati gbe apoti idibo lasiko oṣelu to wa nita bayii lo ti n fa ọpọ awuyewuye, paapaajulọ nipa awọn ti minisita ati gomina banki apapọ Naijiria, Ọmọwe Godwin Emefiele.
Awuyewuye naa tubọ fẹju sii pẹlu bi abala kẹrinlelọgọrin atunto iwe ofin idibo Naijiria tun ṣe sọ ọ di eewọ fun ẹnikẹni to ba wa nipo oṣelu lati dibo tabi gbe igba ibo lasiko idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu wọn.
















