Russia/Ukraine Crisis: Ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV ṣe àkọsílẹ̀ bí àwọn ọmọ ogun Russia ṣe pa aráàlú méjì ní Ukraine

Lati igba ti ogun Russia ti bẹ̀rẹ̀ ni Ukraine iroyin ati ẹ̀sùn n jade pe awọn ọmọ ogun Russia n pa araalu.
Àmọ́, Russia ma n sọ pe irọ ni.
Lọtẹ yii, ẹ̀rọ ayaworan CCTV, ṣe akọsilẹ asiko ti awọn ọmọ ogun Russia pa ọkùnrin kan ati ọga rẹ.
- Ilé tí mo kọ́ ni Ìlànà Omo Oòduà, mi ò lè sá kúrò níbẹ̀ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Okùnrin tó bá ọmọ ọdún 16 lòpọ̀, tó tún ya fọ́tò ìhòhò rẹ̀ dèrò àtìmọ́lé l’Ogun
- Mr Macaroni, Serap, Oby Ezekwesili, Amnesty International faraya lórí Deborah tí wọ́n pa ní Sokoto lórí ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ lódì sí Ànọ́bì
- Ìpàdé ìjọba Nàìjíríààti ASUU lórí ìyanṣẹ́lódì tún forí ṣánpọ́n
- Àwọ̀n ènìyàn rò pé wèrè, ajínigbé ni mí, àmọ́ mo ti kọ́ ilé janturu, fẹ́ ìyàwó mẹ́sàn àn , bí ọmọ 35 – Alfa to n ṣa irin ni atan
- Oloye Adeniji Ige, Mínísítà ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà dágbére fún ayé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún
- Ohun tí a mọ nípa ikọlù àwọn agbébọn sí ilé ìtura ní Ikorodu rèé
Àwọn amofin ni Ukraine ti n wadii fidio naa to tẹ BBC lọwọ, gẹgẹ bi ẹri
Kii ṣe oju ogun ni wọn ti pa awọn ọkunrin mejeeji.
Fidio naa fihan kedere, bi awọn ọmọ ogun Russia to di nkan ijagun mọra, ṣe yinbọn mọ awọn ọmọ Ukraine meji, ti wọn si tun ko ọjà ti wọn n ta.
Nnkan ti a ri ninu fidio naa re e:
Àwọn ọmọ ogun Russia de si agbegbe naa, ninu ọkọ akẹru kan ti wọn jigbe, ti wọn si ṣaami V, ti awọn ọmọ ogun Russia n lo.
Asọ ologun Russia ni wọn wọ.
Bi wọn ṣe n sunmọ ile itaja naa, ni wọn n fa ọ̀pá ibon wọn.
Leonid rin sunmọ wọn, pẹlu ọwọ rẹ loke, lati fihan pe oun ko ni nkan ija dani tabi gbero lati kọjú ija si wọn.
Àwọn ọmọ ogun naa kọ́kọ́ ba oun ati ọga rẹ sọrọ lati ẹyin odi.
- Ó dàbí ẹni pé ẹ kò mọ̀ ìdí tí mo fi ń díje dupò ààrẹ, òhun rè é - Tinubu ṣàlàyé
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Fífún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
Ko si ohùn ninu fidio naa, sugbọn o da bi pe ọkan awọn ọkunrin naa balẹ pe ko sewu. Koda wọn tun fa siga.
Laipẹ, awọn ọmọ Ukraine naa pẹyinda, awọn sọja naa bẹ̀rẹ̀ si ni i lọ.
Lójijì ni wọn yi ẹyin pada, ti wọn yinbọn mọ awọn ọkunrin mejeeji ni ẹyin, laimọye igba.
Lọgan ni ẹni kan ku, amọ Leonid, rọju dide.
Bẹẹ lo ṣe rapala wọ ibi to n gbe, to fi raaye pe ọrẹ rẹ,Vasyl Podlevsky, to ba pe àwọn to ran lọwọ.
Ni gbogbo asiko ti ọkùnrin naa fi n jẹ irora, ti ẹ̀jẹ̀ n jade ni ara rẹ, CCTV fihan pe nise ni àwọn sọja naa n yinbọn bi wọn ṣe n wọ awọn yara ile naa.
Wọn ji ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́, wọn ṣeré ninu ọfiisi ọga, wọn tun tu awọn apoti ẹrù rẹ wo.
Nigba ti àwọn òṣìṣẹ́ adoola, Sasha ati Kostya, de, awọn sọja naa ko jẹ ki wọn o wọlé.
Wọn ni "bi a ṣe n bọ, la n fi ọkan rẹ balẹ, boya yoo fun ni iwuri lati ni amumọra.
" Sugbọn nigba tao fi de ọdọ rẹ, o ti ku. "
Bi wọn tun ṣe n gbiyanju lati gbe oku àwọn ọkùnrin mejeeji, ni àwọn sọja naa tun ju ado oloro.
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ọrẹ Leonid ri pe ẹ̀rọ ayaworan ya ṣe akọsilẹ iṣẹlẹ naa.
BBC fi han ọga ọlọpaa ni ẹkùn Kyiv.
O si sọ fun wa pe oku araalu mẹtadinlogoji ni àwọn tun ri, ti wọn yinbọn pa ni opopona to lọ si olu ilu Ukraine.
Bakan naa ni ileeṣẹ eto idajọ sọ pe oun ti n wadii iku Leonid ati ọga rẹ.
Wọn o lo wọn lati fi ẹ̀sùn iwa ọ̀daràn 'War crimes' kan Russia.
Iku àwọn meji wa lara àwọn to le ni ẹgbẹrun mẹ́wàá ti akọsilẹ ti wa fun.
Iwa ọdaran ni pipa ara ilu lasiko ogun jija, ninu ofin agbaye.





















