Yoruba Nation: Kò sí ẹni tàbí ohun tó le mú mi yi ìpinnu padà lórí Yorùbá Nation - Banji Akintoye

Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ Ìlànà Ọmọ Oòduà káàkiri àgbáyé ti jiyàn rẹ wí pé ìròyìn òfégè ni ìròyìn tí ilé iṣẹ́ Sahara Reporters gbé jáde pé òun ti yọwọ́ nínú ẹgbẹ́ Ìlànà Ọmọ Oòduà.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Banji Akintoye fi léde lọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàlá, ọdún 2022 ni irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé ò ń gbèrò láti pa ẹgbẹ́ Ìlànà Ọmọ Oòduà tí fún ìdí kankan.

Ní ọjọ́bọ̀ ni Sahara Reporters fi ìròyìn kan léde wí pé àwọn kan ti ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àgbọ́forísọ̀pó lọ Akintoye láti yí ìpinu rẹ̀ padà lórí Ilana Omo Oodua.

Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun wí pé àwọn kan ròó wí pé òun yóò tìtorí owó gbàgbé gbogbo ìjìjàgbara tí òun ń ṣe fún Yorùbá nation, kí òun wá gbà láti lọ máa darí ẹgbẹ́ ìkówójọ kan.

Ó ni èyí jẹ́ ìtàbùkù òun àti ríra èébú fún òun.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?

Ó fi kun pé lẹ́nu ìgbà tí àwọn ti dá Ilana Omo Ooduasílẹ̀, ó ti gbòòrò débi wí pé àwọn ọmọ Yorùbá káàkiri ti ń ri gẹ́gẹ́ bí agboòrùn tí wọ́n le sá sí abẹ́ rẹ̀ láti fi gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjọba arẹ́nijẹ, àìsí ètò ààbò àti ètò ọrọ̀ ajé tó ti dorí kodò ní Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára

Ẹnìkankan kò ì tíì gbé owó wá fún mi

Bákan náà ló tẹ̀síwájú wí pé títí di àsìkò yìí, òun kò ì tíì rí ẹnìkankan gbé owó wá fún òun láti ọ̀dọ̀ ìjọba àti pé òun kò lérò wí pé ìjọba le ronú kan òun láti gbé owó fún.

Akintoye sọ síwájú pé ìjọba àpapọ̀ lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Muhammadu Buhari mọ òun dáadáa, tí wọ́n sì mọ̀ wí pé àwọn kò lè fi owó ra òun.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní láìpẹ́ yìí ni ẹ̀yà Yorùbá yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìyà àti ìṣẹ́ tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra, tí ilẹ̀ Yorùbá yóó sì dá dúró èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá àwọn ènìyà inú rẹ̀.

Ó fi kun pé kò sí àníàní tàbí à ń padà sẹ́yìn lórí ìjìjàgbara fún ìdásílẹ̀ Yorùbá nation.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi