2023 Election: Mi ò sí lára àwọn olóṣèlú onírọ́, ọ̀bàyéjẹ́ - Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri, Bola Tinubu ti ni oun ko si lara awọn oloṣelu to n pa irọ nitori ibo lorilẹede Naijiria.
Tinubu sọ eyi lasiko ibẹwo si ipinlẹ Katsina, eleyii to niiṣe pẹlu igbiyanju rẹ fun idibo sipo aarẹ to n bo lorilẹede Naijiria.
Tinubu to n dije dupo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ṣepade pẹlu gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari, awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ ọhun ati awọn aṣoju ti wọn jọ n dije dupo.
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Fí fún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
O ni yatọ si pe oun ni imọ nipa adari lorilẹede Naijiria, oun ṣetan lati sin orilẹede yii pẹlu gbogbo ipa ati agbara oun.
Bakan naa lo fikun un pe oun ko si lara awọn ọbayejẹ to n pa irọ fun awọn eniyan nitori ibo.
Tinubu ni ti ẹgbẹ oṣelu APC ba dibo yan oun gẹgẹ bi ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oṣelu naa ninu idibo to n bọ, yoo jẹ moriya fun oun lati gbogun ti iwa ọdaran ti wọn n koju lorilẹede Naijiria.
Bakan naa lo ṣeleri lati mu idagbasoke ba ina ọba ati eto ẹkọ fun gbogbo awọn ọmọ lai fi ti idile ti wọn ti wa ṣe.
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni bio tilẹ jẹ pe ko si ni ẹni ti ko le e fi ero rẹ han lati dije, kii ṣe gbogbo eniyan lo le di ipo aarẹ mu ni Naijiria.
''Ko si ẹni ti ko le e fi ero rẹ han, amọ awọn oludije yatọ si awọn wọn yii. Oludije ni emi, orilẹede Naijiria yii ti wa si ni. Ki Oluwa bukun fun wa.''
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
- Ṣé lóòtọ́ ní Makinde gbà tíkẹ̀ẹ̀tì Sẹ́nétọ̀ lọ́wọ́ Kola Balogun fún Joseph Tegbe?
Ninu ọrọ tirẹ, gomina naa ni awọn eniyan lo ṣokunfa gbogbo iṣoro ti Naijiria n koju, nitori naa atunṣe wa fun Naijiria.
Bakan naa lo gboriyin fun Tinubu wi pe o jẹ ko ṣeeṣe fun ipinlẹ Eko lati dagba ni abẹ iṣakoso rẹ, ti o si mu adinku ba iwa ọdaran nipinlẹ naa.


















