Zimbabwe Human- Elephant conflict: Ìkọlù àwọn erin ti rán èèyàn 60 lọ sọ́run láàrín ọdún kan lórílẹ̀èdè Zimbabwe

Ọwọ erin kan n jẹ lọ laarin igbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ko din ni ọgọta eeyan ti awọn erin ti pa lorilẹede Zimbabwe lọdun yii gẹgẹ bi ọkan lara awọn agbẹnusọ fun ijọba lorilẹede naa ṣe sọ.

Ninu atẹjade to fi si oju opo Twitter, Nick Manwana ṣalaye pe ohun to ba eniyan ninu jẹ pupọ ni.

"Wahala laarin eniyan ati awọn ẹranko inu igbo ti di eyi to n gbomije loju ọpọlọpọ. Lọdun yii nikan, ọgọta awọn ara Zimbabwe lo ti padanu ẹmi wọn sọwọ awọn erin yii ti aadọta miran si tun fara ṣeṣe loniran an ran.

Lọdun 2021, eeyan mejilelaadọrin lawọn ẹranko naa pa. Orilẹede Zimbabwe yoo ṣepade apero lori ipenija awọn erin loṣu yii."

Ni ileto kan ti wọn n pe ni Bubi, awọn erin wọnyii ti ba gbogbo ere oko jẹ ti wọn si tun ti wa n kọlu awọn ileegbe gbogbo bayii.

O fi kun un pe wọn ti n gbe ija kọlu awọn eniyan, leyi to n mu ki awọn erin ti wọn ba ṣe leṣe wa jingiri ninu iwa ika si awọn olugbe.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?

Ohun ti iwadi n filelẹ ni pe nnkan bi ẹgbẹrun lọna ọgọrun erin lo wa lorilẹede Zimbabwe, ti wọn si n fojumọmọ pọ sii.

Ọkan lara awọn onimọ nipa ẹranko igbo lorilẹede naa ṣalaye fun ileeṣẹ akoroyinjọ AFP pe o ṣeeṣe ki ọrọ naa tubọ maa buru sii.