Muhammadu Buhari yóò gbé ìjọba kalẹ̀ lẹ́yìn sáà rẹ̀ lọ́dùn tó ń bọ̀ - Ijọba Àpapọ̀

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Buhari kò ní fi oṣù mẹ́fà kún ìjọba rẹ̀ bí àwọn kan ṣe ń bèrè - Ìjọba àpapọ̀̀̀

Ijọba apapọ ti sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko ni lo kọja iye ọdun to yẹ ko lo lori oye, bẹẹ ni yoo gbe ijọba silẹ lẹyin saa rẹ loṣu karun un ọdun 2023.

Ṣaaju ni awọn agbẹjọro agba meji ni Naijiria, Aare Afe Babalola ati Robert Clarke ti kọkọ sọ pe o ṣeeṣe ki Buhari ma gbe ijọba silẹ lọdun to n bọ, amọ o le ṣagbekalẹ ijọba fidihẹ ti nnkan ko ba ṣenu ire ni ẹka eto aabo.

Clark sọ pe iwe ofin Naijiria faye gba Buhari lati fi kun akoko rẹ lori oye lọna ati le mu alaafia ba ilu.

Afe Babalola sọ pe o yẹ ki ijọba apapọ gbe ijọba fidihẹ kalẹ, ko si sun eto idibo ọdun 2023 siwaju lọna ati le kọ iwe ofin tuntun, amọ ọpọ araalu ni ko faramọ aba naa.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Erongba ijọba apapọ lori aba naa

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Buhari, Mallam Garba Shehu fi lede, o ni Aarẹ Muhammadu Buhari ko nilo lati ṣafikun ijọba rẹ pẹlu oṣu mẹfa ko to le yanju iṣoro to n koju eto abo Naijria.

Garba Shehu tun kọ aba awọn agbẹjọro agba naa pe ki Buhari fa ijọba le ijọba fidihẹ lọwọ.

O ni ti ijọba Buhari ba ṣe bẹẹ, yoo tẹ ẹtọ awọn ọmọ Naijiria lati dibo yan ẹni to wu wọn sori oye loju mọlẹ.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Kini Garba Shehu tun sọ?

Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe sọ, ijọba Buhari n ṣiṣẹ takun-takun, o si ti n ṣe aṣeyọri ninu igbiyanju rẹ lati mu alafia pada si Naijiria, eyii to gbagbọ pe yoo yanju ko ti di oṣu Karun un ọdun to n bọ to yẹ ko gbe ijọba kalẹ.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

O ni "Oloye Roberk Clerk jẹ ẹni iyi lawujọ, o si le ni erongba rere nipa ọrọ to sọ pe ki Buhari ṣe afikun ijọba rẹ pẹlu oṣu mẹfa, amọ a fẹ jẹ ko ye gbogbo ọmọ Naijiria pe Aarẹ Buhari yoo gbe ijọba kalẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2023 gẹgẹ bii alakalẹ ofin."

"Niwọn igba to jẹ pe Buhari ni oloṣelu akọkọ ti yoo gba ijọba lọwọ oloṣelu ẹgbẹ rẹ ninu ẹgbẹ alatako, ko ni fi ẹtọ araalu du wọn."

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Awọn ẹgbẹ oṣelu n fẹ ki INEC sun gbedeke eto idibo abẹle siwaju:

Ẹwẹ, awọn ẹgbẹ oṣelu kan ti ke si ajọ eleto idibo, INEC, pe ko sun gbedeke ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa siwaju gẹgẹ bii ọjọ ti awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ pari eto idibo abẹle wọn, ki wọn si fi orukọ awọn to n dije du ipo ti wọn yan sọwọ.

Amọ INEC ti sọ ṣaaju ninu atẹjade kan pe oun ko ni sun gbedeke naa siwaju fun awọn idi kan ti oun ko le yẹ.

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso