2023 Presidency: Wo àwọn tó ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Àwọn olùdíje sipo Aarẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Bi gbedeke ọjọ kẹta, oṣu kẹfa ti ajọ eleto idibo Naijiria, INEC fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati ṣeto idibo abẹnu ṣe n sunmọ etile.

Gbigba fọọmu sipo Aarẹ Naijiria lábẹ́ àsìá ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti wa sopin.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo figbe bọnu lori ayelujara nigba ti APC gbe sita wi pe ọgọrun-un miliọnu Naira ni awọn yoo ta fọọmu naa sibẹ ko din ni ogun awọn oloṣelu kaakiri Naijiria lo ra fọọmu naa.

Ni bayii ti tita fọọmu naa ti wa sopin BBC News Yoruba ṣe akojọ orukọ awọn to ra fọọmu naa.

Awọn naa ni:

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

TINUBU

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Tinubu to jẹ ọkan gboogi lara awọn ọludasile ẹgbẹ ọselu APC ṣe gomina ipinlẹ Eko fun ọdun mẹjọ laaarin ọdun 1999 si 2003.

Ẹni ọdun mọkanlelogoji ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu wa to fi di Gọmina Ipinle Eko ti o si ni ọpọlọpọ ipa ninu idagbasokẹ ipinlẹ Eko.

Gomina Yahaya Bello

YAHAYA BELLO

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gọmina Yahaya Bello, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ni gọmina ipinlẹ Kogi lọwọ lati bi ọdun mẹjọ sẹyin ti o si fẹ tẹsiwaju lati sẹ Aarẹ orilẹ-ede Naijiria ninu ẹgbẹ ọselu APC.

Gomina Dave Umahi

Gomina ipinlẹ Ebonyi ni Dave Umahi, ọmọ ọdun mejidinlọgọta ni n ṣe to si ti n lo ọdun mẹjọ lọ gẹ́g.ẹ́ bi gomina bayii.

Umahi ti fi erongba sita fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati di Aarẹ ni ọdun 2023 ninu ẹgbẹ ọselu APC.

Sẹnetọ Rochas Okorocha

OKOROCHA

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọmo ọdun mọkandinlọgọta ni Asofin Rochas Okorocha. O wa lati guusu Ideato ni ipinle Imo. Okorocha jẹ gomina ipinlẹ Imo fun ọdun mẹjọ, ki o to tẹsiwaju lati soju awọn eeyan Imo west ni ile aṣofin agba lati ọdun 2019

Uju Kennedy

Abilekọ Uju Kennedy ni obinrin kan ṣoṣo to ra fọọmu lati dupo Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Apc ninu gbogbo awọn obinrin to fi erongba wọn han.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Ibikunle Amosun

Lẹyin ti o di sẹnetọ ni odun 2003 lati sọju aarin gbungun ipinlẹ Ogun, Amosun jẹ gọmina ipinlẹ Ogun fun ọdun mẹjọ.

Nigba ti o pari saa re gẹgẹ bi gọmina, Amosun pada si ile asọfin agba orilẹ-ede Naijiria ti oun naa si wa lara awọn to ti ra fọọmu lati dupo Aarẹ Naijiria bayii labẹ ẹgbẹ ọselu APC.

Pasitọ Tunde Bakare

PASITỌ TUNDE BAKARE

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Oluṣọ Aguntan ati alamojuto ijọ Citadel Global Community Church (CGCC) naa kede erongba rẹ lati tukọ Naijiria ni kete ti Aarẹ Buhari ba ti pari saa rẹ lọdun to n bọ ti o si ti fọọmu.

Ni ọdun 2011, ọlusọ aguntan Tunde Bakare jẹ amugbalẹgbẹ Aare Muhammodu Buhari ninu ẹgbẹ ọselu CPC.

Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo

YEMI OSINBAJO

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Igbakeji Aarẹ Muhammadu Buhari, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo naa ti kede ipinnu rẹ lati wọ bata ti ọga rẹ ba bọ kalẹ lọdun to n bọ.

Osinbajo to jẹ́ Agbẹjọrọ Agba, to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun bẹrẹ ọsẹlu gẹgẹ bi Kọmiṣọna feto idajọ ati agbajẹro agba ipinlẹ Eko labẹ iṣejọba Tinubu.

Nicholas Felix

Ọlusọ aguntan yii to jade dupo Aarẹ ni ọdun 2019 labe ẹgbẹ ọṣelu Peoples Coalition Party (PCP) ti o si gbe ipo kẹrin naa tun ti fi erongba rẹ lati tun gbiyanju lẹẹkan si han labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Kayode Fayemi

Ọmọ odun mẹtadinlọgọta ni gọmina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, ẹni to jẹ minisita ẹto alumoni lati ọdun 2015 si ọdun 2018 ko to kọ iwe fi ipo silẹ lati dupo gomina ipinlẹ Ekiti.

Rotimi Amaechi

Gọmina ana ni ipinlẹ Rivers naa darapọ mọ idije lati dupo Aarẹ ọdun 2023 labẹ ẹgbẹ ọselu APC. Amaechi lo jẹ gọmina fun ọdun mẹjọ ni ipinlẹ Rivers ki o to di Minisita fun iriina lati ọdun 2015.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Ken Nnamani

Ọmọ odun Metalẹlaadọrin lati ipinlẹ Enugu ati Aare ana fun ile igbinmọ aṣoju ṣọfin agba ni Ken Ugwu Nnamani. Ken Ugwu Nnamani naa kẹdẹ erongba rẹ lati di aare orilẹede Naijiria ni ọdun 2023

Chris Ngige

CHRIS NGIGE

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Minisita fọrọ oṣiṣẹ labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari ni Chris Nwabueze Ngige to si jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Anambra.

Governor Abubakar Badaru

Gọmina ipinlẹ jigawa lati bi odun meje ni gọmina Badaru. Badaru ni oun fẹ tẹsiwaju lati soju ọmọ orilẹede Naijiria gẹgẹ bi Aarẹ ni ọdun 2023 ninu ẹgbẹ ọselu APC.

Dimeji Bankole

Ni ọjọ mẹta yii ni iroyin gba ori ayelujara kan wi pe Abẹnugan tẹlẹ ri yii fun ile igbimọ aṣojuṣofin ti ra fọọmu lati dije dupo Aarẹ Naijiria.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Godwin Emefiele:

Ni ọjọ meloo sẹyin ni awọn agbẹ kan ra fọọmu oludije sipo Aarẹ fun gomina fun banki apapọ orilẹede Naijiria Godwin Emefiele.

Emefiele to ti n ṣe gomina CBN lati ọdun 2014 je ọmọ agbegbe guusu ni ipinlẹ Delta.

Senator Ajayi Boroffice

Ọjọgbọn Robert Ajayi Boroffice jẹ ọmọ ọdun mẹtalelaadọrin lati ipinlẹ Ondo.

Senator Ajayi Boroffice ṣoju ẹkun idibo ariwa ipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Ogbonnaya Onu

Ogbonnaya Onu jẹ gomina akọkọ ijọba awaarawa fun ipinlẹ Abiako to di Minisita fun imọ ẹrọ ati sayẹnsi.

Akinwumi Adesina

Akinwumi Adesina ni Aarẹ fun ile ifowopamọ idagbasoke ilẹ Adulawọ.

Adesina ti sẹ minisita fun eto ọgbin ko to lọ si African Development Bank ni ọdun 2011.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji