BBC Investigation on IPOB: Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra

IPOB

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipob: Awọn ọmọ ikọ ẹgbẹ agbesunmọmi to n gbe oju opo ayelujara da rugudu silẹ

Iwadii ileesẹ iroyin BBC kan ti tu asiri lori bi awọn ọmọ ikọ Ipob kan se n lo ojuopo ayelujara lati maa fi tan ọrọ inunibini ati ipaniyan ka lori awọn to tako idasilẹ Biafra.

Ikilọ ree, o ni awọn aworan kan ninu apilẹkọ yi ti ọkan rẹ le kọ

Loju opo Facebook Live,Efe Uwanogho taa tun mọ si Omote Biafra n se ipolongo ọrọ inunibini sawọn ololufẹ rẹ.

O wọ jakẹẹti kan ti wọn ya aworan idanimọ Biafra si.

''Ẹ wa awọn obilẹjẹ yi kan, awọn leeyan to yẹ ki wọn bẹ lori.Awọn lo yẹ ki wọn dana sun di eeru''

O n pe fun ikọlu fawọn to ka si alatako idasilẹ Biafra eleyi ti yoo mu ki ilẹ Igbo ya pa kuro lara Naijiria.

Ipolongo ominira Biafra yi jẹ eyi to ni akọsilẹ itajẹsilẹ latẹyinwa.

Lọdun 1967.awọn ajijagbara lati ilẹ Igbo kede ominira ilẹ Biafra.

Ọdun mẹta ni wọn fi ba ijọba Naijiria jagun eleyi ti wọn fidirẹmi ninu rẹ.

Eeyan to ku le ni miliọnu kan.Ọpọ si wa lati ọdọ awọn ajijagbara yi.

Omo ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin nkan bi aadọta ọdun le diẹ oju opo ayelujara ti di ibugbe fawọn mii to n tẹsiwaju pẹlu ipe ominira yi.

Arabinrin Uwanogho wa lara wọn.

O jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ogun oju opo ayelujara fẹgbẹ ajijagbara ti wọn n pe ni: Indigenous People of Biafra (Ipob).

Àkọlé fídíò, #BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC

Lati orile-ede Italy lo ti n kan si awọn eeyan nibi ti ọwọ awọn alasẹ Naijiria ko le tẹ.

Ni Naijiria ijọba ti fofin de ẹgbẹ yi ti wọn si kede rẹ gẹgẹ bi agbesunmọmi.Ipob si n tẹ nu mọ pe ẹgbẹ alaafia lẹgbẹ awọn.

Iwadii BBC fihan pe ọpọ awọn sọrọsọrọ Ipob loju opo ayelujara maa n fi ọrọ ti kiis e ootọ sita ti wọn a si tun maa pe fun ikọlu lati awọn ilẹ Yuroopu, ilẹ Amẹrika, Asia ati awọn apa ibomiran nilẹ Afrika.

Akọroyin oniwadi Naijiria nii,Nicholas Ibekwe sapejuwe awọn to n sọrọ lori aylejara yi gẹgẹ bi''agbarijọpọ awọn to n sọrọ inunibini loju opo ayelujara''

O ni "oju opo ayelujara ni irinsẹ to munadoko fun wọn lati se nkan ti wọn n se loni''

Bawo ni wọn ṣe n ṣiṣẹ?

O kere tan ẹgbẹgbẹrun awọn ololufẹ lo n tẹle oju opo awọn wọnyi loju ayelujara.

A ko mọ boya awọn ololufẹ arabinrin Uwanogho kankan ti sọ ọrọ to n sọ funwọn di imusẹ lati se ikọlu sawọn alasẹ lagbegbe ilẹ Igbo.

Nigba ta kan si arabinrin Uwanogho lati bawa sọrọ lori apilẹkọ yi, o kọ lati dawa lohun.

Nneka Igwenagu ati Efe Uwanogbo n karoyin lati ile okeere
Àkọlé àwòrán, Nneka Igwenagu ati Efe Uwanogbo n karoyin lati ile okeere

Amọ ni nkan to wa nilẹ bayi,ikọlu a maa waye lootọ.

Aimọye awọn osisẹ lo ti padanu ẹmi wọn ninu awọn ikọlu to waye lọdun yi nikan.

Aarẹ Buhari sapejuwe ikọlu yi gẹ́gẹ bi ''eleyi to bani lọkan jẹ gidi gan an''

Nneka Igwenagu naa jẹ ọkan lara awọn ọmọ ogun ayelujara to n ja fun Biafra lati ilẹ Gẹẹsi.

Ninu ọrọ to kọ soju opo Facebook lati London lọdun 2021, o fi ọrọ tako awọn ikọ ọdọ kan ti wọn kọ lati wọgile karakata ni Anambra bi Ipob se n sọ pe ki wọn se lati le fi se atilẹyin fun adari Ipob, Nnamdi Kanu to wa ni ahamọ.

Adari ikọ IPOB, Nnamdi Kanu to fọwọsi ọpọ iṣesi awọn ọmọ ogun lori ayelujara IPOB

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Adari ikọ IPOB, Nnamdi Kanu to fọwọsi ọpọ iṣesi awọn ọmọ ogun lori ayelujara IPOB

Olori Ipob, Kanu ti gbosuba kare fawọn ọmọ ogun oju opo ayelujara yi.

O wa ni ahamọ lọdọ awọn alasẹ Naijiria lori ẹsun igbesunmọmi eleyi to ni oun ko jẹbi.

Arabinrin Igwenagu nigba to n sọrọ lede Igbo sapejuwe awọn ti ko fẹ darapọ mọ Ipob yi gẹgẹ bi ọlẹ lasan to si ni:''Ko yẹ ki gbogbo yin wa laye rara.Adiẹ to gbe ẹyin ara rẹ jẹ, Njẹ ẹ ko ri pe ko yẹ ki ẹ wa laye ni?''

Nkan bi ọsẹ meloo kan lẹyin ọrọ to polongo yi, olori awọn to n tako ọrọ si yi lawọn kan yinbọn lu ti wọn si pa.

Adari ọdọ Ogidi ti wọn n ki lroi ayelujara lẹyin ipapoda rẹ
Àkọlé àwòrán, Adari ọdọ Ogidi ti wọn n ki lroi ayelujara lẹyin ipapoda rẹ

Ko yi si eeyan kankan ti wọn mu lori iku rẹ.

Loju opo ayelujara nise lawọn eeyan kẹdun iku olori ọdọ Ogidi yi lẹyin iku rẹ.

A kan si arabinrin Igwenagu lati sọ tẹnu rẹ lori isẹlẹ yi sugbọn ko fesi pada.

Ọna kan tawọn ọmọ ogun oju opo ayelijara yi maa n lo lati fi bọ mọ awọn ti yoo fofin de wọn lojuopo ayelujara ni bi wọn se maa nsọ adalu ede.

Ninu fọnran kan ta se alabapade a ri apẹrẹ iru ọgbọn ti wọn nd ayi.

Okenna Okechukwu, taa tun mọ si Biafran Child,bẹrẹ ọrọ rẹ ni ede Igbo nibi to ti n pe fun ibẹlori alatako kan.

Lẹyin naa lo yi ọrọ rẹ si ede Igbo lati le fi salaye fawọn alatilẹyinrẹ pe :

''Idi ti mo fi n sọ ọrọ yi ni ede mi ni pe mi o fẹ ki wọn di mi lọwọ.Mi o fẹ ki wọn gbegi dina oju opo mi yi''

David Ajikobi, olootu ileesẹ to n sayẹwo ọrọ to ba jẹ ootọ taa mọ si Africa Check sọ pe aisi ọna lati maa mojuto ọrọ inunibini lawọn ede abinibi kii se ipenija to n koju Naijiria nikan loju opo ayelujara.

"A ti ri iru rẹ ni India,ni Ethiopia awọn ibi ti wahala ti n sẹlẹ,awọn eeyan a maa lo ede abinibi wọn nitori wọn mọ pe ti wọn ba lo ede Gẹẹsi, Facebook yoo wọ ojuopo wọn danu ti yoo si gba wọn yọ kuro''

Toun ti bi ọrọ inunibini se pọ to loju opo ayelujara, fifi ofin de wọn ko duro deede.

Àkọlé fídíò, Idibo ko ni waye ti wọn ko ba mu ọkọ mi jade

Apẹrẹ kan ree:

Ni ibamu pẹlu ilana Facebook lori awọn ọrọ inunibi, a fẹjọ Efe Uwanogho ati Nneka Igwenagu sun lori awọn ipolongo ti o ni ọrọ inunibini ninu.

Facebook kọkọ fi esi ransẹ poe awọn ti ri ẹsun taa fi kan awọn wọnyi ti wọn si lawọn pinu pati ma se yọ fidio wọn kuro loju opo naa.

Asẹyinwa asẹyinbọ ni wọn to yọ wọn kuro nigba taa fi oju opo ibi ti wọn ti n sọ ọrọ yi ransẹ si Facebook.

Amọ awọn ọrọ mii to jọ iru eleyi taa fẹjọ rẹ sun si wa loju opo Facebook titi di akoko ta fi gbe apilẹkọ yi sita.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?

Dida wahala silẹ:

Olu ileesẹ Facebook,iyẹn Meta sọ fun wa ninu atẹjade kan pe loju opo Facebook,awọn lodi si ipe eyikeyi lati se ikọlu sawọn eeyan.

O ni awọn gba osisẹ lede orisi to le ni ẹgbẹrun mẹẹdogun lati maa se ayẹwo ọrọ loju opo wọn.

Ede Igbo si wa ninu ede wọnyi.

Iwadii wa fi han pe awọn alatilẹyin Ipob kan naa n bawọn runa si dida wahala silẹ laarin awọn ẹya Naijiria.

Awọn ọ́mọ ogun oju opo ayelujara yi a maa da wahala silẹ laarin ẹya Kristẹni to wa ni Guusu Naijiria ati awọn Fulani to jẹ musulumi ti wọn si wa lati ariwa Naijiria.

Ninu ọrọ miran loju opo Facebook,arabinrin Igwenagu n kilọ fawọn alatilẹyin rẹ pe ''awọn darandaran Fulani ati awọn eeyan ariwa mii ti sigun wa si ilẹ Igbo lati wa pa wa, ki wọn si pa awọn ẹya Igbo rẹ''

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Se wọn n san owo fun wọn lori iru ọrọ inunibini yi ni?

Bo ti lẹ jẹ wi pe ikọlu ti n waye laarin awọn Fulani darandaran ati awọn ẹya Igbo ko si ẹri aridaju pe lootọ ni ọrọ ti arabinrin Igwenagu n sọ.

Iru ọrọ to le da ija silẹ yi le jẹ pe nitori idasilẹ Biafra ni o se n waye sugbọn iwadii wa naa fi han pe o le ni anfaani owo kan ti wọn n ri nibẹ.

A sawari awọn fidio kan nibi tawọn ọmọ ogun oju ayelujara Biafra yi ti n sọ pe wọn san owo fawọn yala lati ọdọ Ipob tabi awọn alatilẹyin wọn lori isẹ ti wọn n se yi.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Bẹẹ la ri awọn fidio miran nibi ti wọn ti ni kawọn eeyan maa san owo si akoto owo Biafra lati se atilẹyin fun wọn.

Akọroyin Nicholas Ibekwe wa lara awọn akọroyin to n bẹnu atẹ lu awọn ileesẹ oju opo ayelujara lori ai gbiyanju to lati koju lilooju opo wọn fawọn ipolongo aburu yi.

O dabi ẹni pe gbogbo awọn to wa ni Facebook ti sun asunpara.Wọn ko tiẹ se ise pe awọn ọrọ inunibini to wa loju opo wọn yi n da wahala silẹ rara''

Audu Linus ati Gloria Mathew ti wọn kọlu nigba ti wọn n lọ se igbeyawo wọn

Ẹwẹ ikọlu sawọn eeyan ko dawọ duro.

Lọgbọn ọjọ osu Kẹrin ọdun 2022, Audu Linus ati Gloria Matthew ti wọn jijọ jẹ ọmọ ogun Naijiria n dari lọ si ilu wọn lati lọ se eto igbeyawo wọn ni ipinlẹ Imo nigba tawọn kan ji wọn gbe, ti wọn fi iya jẹ wọn ti wọn si tun pa awọn mejeeji.

Fidio taa ri to safihan bi wọn se pa awọn mejeeji yi eleyi ti ijọba Naijiria dẹbi rẹ ru ikọ Ipob.

Lẹyin igba naa lawọn alatilẹyin Ipob bẹrẹ si ni fi ahesọ ọrọ sita pe wọn ko pa awọn mejeeji ni tootọ ati pe wọn da bi ọgbọn ni.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

BBC ti tẹsiwaju lati kan si mọlẹbi awọn ọmọ ogun mejeeji yi ti wọn si fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni wọn seku pa wọn.

Ipob lawọn ko lọwọ ninu isekupani awọn wọnyi.

A kan si awọn olori ikọ Ipob pẹlu abajade iwadii wa .

Wọn da wa lohun sugbọn wọn ko sọ nkankan nipa isẹlẹ yi.

Bẹẹ naa la kan si gbogbo awọn ọmọ ogun ayelujara ti a sọrọ nipa wọn ninu apilẹkọ yi ki awọn naa fesi si nkan to sẹlẹ.

Wọn ko sọ nkankan lori rẹ.