Sit at home Ipob: Ẹgbẹ́ IPOB kéde kónílé-ó-gbélé ọ̀sẹ̀ kan lásìkò tí ìdìbò gómìnà Anambara yóò wáyé

Awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB lasiko iwọde wọn

Ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, IPOB ti kede iwọde ọlọsẹ kan gbako jakejado ilẹ Igbo, bẹrẹ lati ọjọ karun-un si ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla.

Ipob sọ pe iwọde ati ofin konile-o-gbele naa jẹ ọna lati mu ki ijọba apapọ tu Nnamdi Kanu silẹ.

Ṣugbọn ṣa, ikede naa waye lasiko ti idibo gomina ipinlẹ Anambra ku diẹ. Ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla ni idibo naa yoo waye.

Akọwe ipolongo fun IPOB, Emma Powerful, to fi ikede naa sita ni ọjọ Satide sọ pe:

"Lẹyin ti wọn ti sun igbẹjọ olori wa, Mazi Nnamdi Kanu, si ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, awa ọmọ ẹgbẹ IPOB n kesi awọn ọmọ ilẹ Biafra, awọn ọrẹ Biafra, ati awọn to fẹran ominira, pe IPOB yoo da gbogbo nkan duro ni ilẹ Biafra, bẹrẹ lati ọjọ karun-un si ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla."

O ni ọjọ Aiku nikan ni anfaani wa fun awọn eeyan lati jade, ki wọn o le lọ sin Ọlọrun.

Powerful sọ pe awọn yoo gbe igbesẹ naa, ti ijọba Naijiria ba fi kuna lati tu Kanu silẹ lai gba ẹjẹ kankan titi ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla.

O ni lootọ ni awọn mọ inira ti ofin konile-o-gbele naa ni lara awọn araalu, ṣugbọn o jẹ dandan nitori ki ki nkan le dara fun gbogbo ọmọ Biafra.

Ọgbẹni Powerful tẹsiwaju pe awọn ko ni i gba ki wọn o ma a ṣe igbẹjọ Kanu ni bonkẹlẹ, tabi labẹ ofin Sharia.

O sọ eyi nitori bi awọn oṣisẹ alaabo ko ṣe jẹ ki ẹnikẹni wọle sinu gbọngan igbẹjọ rẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa.

IPOB ni awọn yoo jẹ ki ijọba Naijiria mọ pe aadọrin miliọnu eeyan to jẹ ọmọ Biafra, ni Nnamdi Kanu n ṣoju.