Jigawa Cholera Outbreak: Àrùn onígbáméjì pa èèyàn 500 ní Jigawa, 720 gba abẹ́rẹ́ àjẹsára

Oríṣun àwòrán, Ournaijanews
Ko din ni ẹẹdẹgbẹta eeyan to ti jẹ Ọlọrun nipe bayii lẹyin ti ajakalẹ arun onigba meji bẹ silẹ ni ipinlẹ Jigawa laarin oṣu mẹrin.
Pẹlu iye awọn eeyan to n ku yi, ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe ko din ni ẹgbẹrun lọna ogun eeyan lo ti fara kasa arun naa nipinlẹ ọhun.
Ijọba ibilẹ mejilelogun ninu ijọba ibilẹ mẹtadinlọgbọn ni arun naa ti n fi logbologbo bayii.
- Kìí ṣe nǹkan ìtìjú pé èmi ni mò ń gbọ́ bùkátà ẹbí mi - Nkechi Blessing
- Ta ni yóò jẹ Ọba dá ìjà sílẹ̀, òjò làásìgbò ń sú ni Iralepo Isinkan nílùú Akure
- Nítorí owó, ọlọ́pàá obìnrin kan pa mọ̀lẹ́bí rẹ̀ márùn-ún àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀
- Àwọn agbébọn ya wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Oyo, wọ́n tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀
- Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa bí "Flubot Malware" ṣe lè kọlu fóònù yín lójijì? - NCC
- Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua
- Báwo ni orísun omi ilẹ̀ Adúlawọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la ṣe péye tó ní ìlú àti orílẹ̀èdè rẹ-
- Ọ́ọ́físà tó lu Clement awakọ̀ Uber níbi EndSARS gba ìwé máa lọ ilé ná
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram kan gẹ́gẹ́ bí Malami ṣe sọ?
Lara awọn ibi ti arun onigbameji ọhun ti milẹ julọ ni olu ilu ipinlẹ ọhun, Dutse, to fi mọ ilu Birninkudu ati Hadejia.
Akọwe agba ileeṣẹ to n ri si eto ilera alabọde nibẹ, Kabir Ibrahim ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣe takun-takun lati pana arun ọhun.
Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn akọroyin kan niluu Dutse, Kabir sọ pe awọn ti fun ẹẹdẹgbẹrin ati ogun eeyan, 720, labẹrẹ ajẹsara arun naa.
O ni "A ti tẹwọgba miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna irinwo abẹrẹ ajẹsara lati ọdọ ajọ eto ilera agbaye, WHO, awọn ọmọ ọdun kan si agbalagba lo si lẹtọ lati gba abẹrẹ ajẹsara naa.
"Lọwọ yii, ijọba ibilẹ meji ti arun naa ti ṣọṣẹ julọ ni a kọkọ fẹ bojuto, awọn eeyan naa yoo si gba abẹrẹ ọhun nigba meji ọtọtọ laari ọsẹ mẹrin sira wọn."
Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ilu lati ṣatilẹyin fun ijọba lori akitiyan rẹ lati kapa arun naa.
Ẹwẹ, iwadii ti ajọ WHO ṣe ti fi han pe o le ni miliọnu kan eeyan to n lugbadi arun onigabmeji lọdọdun, ti nnkan bii ẹgbẹrun mọkanlelogun si ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan si n ba arun naa lọ.














