Road Accident: ìjàmbá ọkọ̀ ṣekúpa ènìyàn kan ní agbègbè Costain ní Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrí ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA ti doola ẹmi arabinrin kan ti kọntena ẹyin ọkọ jabọ le lori ni agbegbe Costain ni ipinlẹ Eko.
Ni alẹ ọjọru, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2022 ni ijamba naa waye to si tun ṣokunfa iku arakunrin kan.
Gẹgẹ bi atẹjade latọwọ olori ẹka iroyin LASEMA, Nosa Okunbor ṣe sọ, awọn Osujumikoro ti iṣẹlẹ naa waye loju wọn ni lasiko ti awọn ọkunrin ati obinrin ọhun n rin lọ ni kọntena ọhun yẹ labẹ ọkọ rẹ to si ṣe akoba fun awọn mejeeji.
- Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Fí fún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ọwọ́ tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìtura, wo nǹkan tí ọlọ́pàá ká mọ lọ́wọ́
Bi o tilẹ jẹ pe obinrin ko jẹ Ọlọrun ni pe ni tirẹ, o ṣeni laaanu pe ẹsẹ rẹ ba iṣẹlẹ naa lọ.
Okunbor ṣalaye wi pe ni nnkan bi aago mejila ku iṣẹju mẹtadinlogun oru ni ipe wọ ori ẹrọ ibanisọrọ awọn ti awọn si yara de ibẹ.
O ni nigba ti awọn yoo fi de bi iṣẹlẹ naa, ẹmi ọkunrin naa ti bọ nitori bi kọntena naa ṣe jabọ le lori ṣugbọn awọn ribi doola ẹmi obinrin labẹ rẹ ṣugbọn ẹsẹ rẹ ti da.
O fi kun pe àwọn ti gbe oku ọkunrin naa fun ẹka to n ri si ọrọ ayika ipinlẹ Eko fun igbesẹ to ba kan ti awọn si ti gbe obinrin naa lọ si ile iwosan.
Bakan naa lo fi kun pe awọn ti fa ọkọ nla to ṣokunfa ijamba naa le ileeṣe ọlọpaa lọwọ.
"Opopona naa ni o ti wa fun lilo awọn ara ilu lẹyin isẹlẹ naa."


















