Nkechi Blessing and Opeywmi Falegan: Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan

Oríṣun àwòrán, Nkechi blessing sunday/instagram
Wahala tun ti n rugbo bọ, laarin gbajumọ oṣerebinrin, Nkechi Blessing ati ọrẹkunrin rẹ nigba kan, Opeyemi Falegan.
Tẹ o ba gbagbe, ibẹrẹ oṣu Kẹrin ni ipinya waye laarin awọn mejeeji to ti fi igba kan jẹ ololufẹ.
Lasiko naa, niṣe ni wọn n gba eebu, epe ati titu aṣiri ara ẹni sita bi ẹni gba igba ẹmu, loti ayelujara.
Eyi waye fun bi ọsẹ kan si meji gbako.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti Ọgbẹni Falegan tọrọ aforiji lọwọ Nkechi ni ọjọ diẹ sẹyin.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lori ayelujara pẹlu gbajumọ agbohunsafẹfẹ, Ifedayo Olarinde, Daddy Freez lọjọ Iṣẹgun lo ti ṣe eyi.
- Mo tọrọ àforíjì pé mo parọ́ ìgbéyàwó! Mi ò ṣe ìgbéyàwó kankan!
- Genevieve Nnaji fi fídíò sí Instagram, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìròyìn sọ pé ó ní àrùn ọpọlọ
- Johnson Sulemann sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn tí Stephanie Otobo fi kàn án
- Báwo ni ọ̀rọ̀ ilé ṣe fa Gbas-gbos láàrín Mercy Aigbe, ìyáále rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀?
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ọwọ́ tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìtura, wo nǹkan tí ọlọ́pàá ká mọ lọ́wọ́
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
- PDP wọ́gilé ìlànà jẹ kí n jẹ 'zoning' fún yíyan olùdíje ipò ààrẹ
Ninu ifọrọwerọ naa, Falegan sọ pe tinutinu ni oun fi tọrọ idariji. Ati pe ninu ọkan oun , oun ṣi nifẹ osẹre naa.
"Mo gba pe mo hu awọn iwa ẹgbin si ọ.
"Lati inu ọkan mi, mo ṣi nifẹ rẹ. Ti ẹ ba ri, ẹ ba mi sọ fun pe mo nifẹ rẹ.
"Jẹ ki awọn nkan to ṣẹlẹ tẹlẹ, di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ."
O ṣapejuwe Nkechi gẹgẹ bi eeyan daadaa, ati oniwa rere to rọrun lati fi ifẹ han.

Oríṣun àwòrán, Nkechi blessing sunday/instagram
Ṣe lootọ ni wọn ṣe igbeyawo?
Ṣaaju ki wọn o to tuka, ọkọ ati iyawo ni Nkechi ati Opeyemi ma n pe ara wọn.
Bakan naa ni Nkechi ma n wọ oruka igbeyawo, eyi to mu ọpọlọpọ eeyan gbagbọ pe wọn ti ṣe igbeyawo.
Yatọ si eyi, ọpọ igba ni wọn jọ ya fọto ninu aṣọ anko.
Amọ nigba to n sọrọ, Opeyemi sọ pe ootọ ni awọn nifẹ ara wọn.
O ni to ba jẹ pe eeyan radarada ni oun ko ni i ma fi oun han araye, bẹẹ ni oun paapaa ko ni maa pe ni iyawo oun.
"Ko si igbeyawo kankan ni aarin wa, sugbọn ifẹ wa.
- Ọkọ mi tẹ́lẹ̀ àti Adekaz kò fi ìgbà kankan jẹ́ ọ̀rẹ́, kìí sẹ ọ̀rẹ́ ọkọ mi ni mo fẹ́ - Mercy Aigbe
- Ọwọ́ tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìtura, wo nǹkan tí ọlọ́pàá ká mọ lọ́wọ́
- Olùkọ́ Chrisland College mẹ́rin fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀
- Kọ́ńdọ̀ọ̀mù méjìlá lá rí ní iyàrá ilé ìtura tí wọ́n ti fípa bá arábìnrin Ulochi lòpọ̀- Olọ́pàá
- Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly ní Nàìjíríà , ASUP bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì, wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
O ni Nkechi ko ri ẹbi oun kankan ṣoju ri. Bẹẹ ni oun ko fun ni oruka adehun igbeyawo.
"Lootọ ni mo ro pe a le ṣe igbeyawo, ṣugbọn awọn nkan ti mo ri ko mu ko jẹ ẹni ti mo le fẹ."
'Ọbun ni Nkechi, pata kan lo n wọ fun ọjọ mẹta'
Bo tilẹ jẹ pe Falegan gbe oriyin fun Nkechi ṣaaju, iyalẹnu lo jẹ nigba to tun fi fidio mii sita lati tabuku rẹ.
O ni oun tọrọ aforijin lọwọ Nkechi ki awọn le gbagbe ọrọ ana, kii ṣe nitori ki awọn le di ololufẹ pada.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Falegan sọ pe idi ti oun fi fi Nkechi silẹ ni pe o ni ọbun, kii fọ pata tabi fọ eyin rẹ lai jẹ pe oun sọ fun.
"Emi ni ma a sọ fun obinrin pe ko paarọ pata lẹyin ọjọ kẹta, ran leti pe ko fọyin ni owurọ.
"Mi o le faramọ iru nkan bẹẹ."
Lati ọmọ ọdun mejidinlogun ni mo ti wọ pata kẹyin - Nkechi Blessing
Nkechi fesi fun Falegan lori ọrọ pata didọti
Ko pẹ ti Falegan fi ẹsun iwa ọbun kan Nkechi, ni oun naa fesi loju opo Instagram storiee.
O ni nkan to han si gbogbo eniyan ni pe oun kii wọ pata, lati igba ti oun ti wa ni ọmọ ọdun mejidinlogun.
"Emi NBS pẹlu pata kẹ? Mi o ni pata kan ṣoṣo boti wu ko kere mọ."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Nkechi sọ pe irọ patapata ni ọrẹkunrin oun tẹlẹ pa mọ oun, nitori pe oun kii sun mọ ohunkohun ti wọn n pe ni pata rara.
"Irọ ti o pa yii, ni Ọlọrun fi wẹ mi mọ lori gbogbo nkan to ṣẹlẹ laarin emi ati ẹ."
Ohun to yẹ ki o mọ niap oṣerebinrin, Nkechi Blessing
Nkechi Blessing Sunday ni apeja orukọ rẹ.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 1989 ni wọn bi si agbegbe Surulere nipinlẹ Eko.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ẹya Igbo ni lati ipinlẹ Abia, oṣere Yoruba ni.
Ọdun 2008 lo kopa fun igba akọkọ ninu fiimu kan, Omo Bewaji.
O si ti kopa ninu fiimu to le ni ọgbọn lati igba naa.























