ASUU Strike, learn handi work: Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀

Irin iṣẹ owọ

Oríṣun àwòrán, Others

Aṣalẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu Karun un, ọdun 2022 yii ni ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU, kede pe awọn yoo fi oṣu mẹta kun iyanṣẹlodi wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun yii ni iyanṣẹlodi naa bẹrẹ lẹyin ti ijiroro laarin awọn ijọba apapọ fori ṣọpan.Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ti ASUU yoo gunle iyanṣelodi ree, ọpọ awọn akẹkọọ loti n ṣe ifẹhonuhan kaakiri Naijiria lori iyanṣẹlodi naa, ti awọn mii ninu wọn si ti gbakamu.

Wayi o, ni bayii ti ASUU ti sọ pe awọn akẹkọọ yoo lo oṣu mẹta mii si nile, BBC Yoruba ṣe akọjọpọ awọn iṣẹ meje pataki ti awọn akẹkọọ le kọ lasiko isinnmi alailọjọ naa.

Awọn iṣẹ ti o le kọ lasiko iyanṣẹlodi oṣu mẹta ASUU ree:

Iṣe aranṣọ

Iṣẹ aranṣọ jẹ ọkan lara awọn iṣẹ to gbajumọ julọ lakoko yii nitori oge ṣiṣe awọn ọdọ.

Ọpọ awọn akẹkọọ mii to lọ ile ẹkọ lo maa n pada lọ kọ iṣẹ naa ti wọn pari ẹkọ wọn tan, nitori naa, asiko to yẹ lati kọ iṣẹ naa ree ti wọn wa ni isinmi ọlọjọ gbọọrọ.

O ṣeeṣe ki eeyan ma le dantọ nidi iṣẹ yii laarin oṣu mẹta epere, amọ iruf̣ni bẹẹ le pada ṣẹnu iṣẹ ọhun to ba ti pari ẹkọ rẹ tan.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Iṣẹ onidiri ati aṣerunniyọyọ

Iṣẹ onidiri tabi iṣẹ aaṣerunniyọyọ jẹ ọkan lara awọn ịṣẹ to ti wa fun ọjọ pipẹ, iṣẹ naa kii si kuta nitori awọn onibara yoo maa wa niwọn igba ti awọn eeyan ba n ni irun lori.

Iṣẹ yii ko yọ okunrin tabi obinrin silẹ.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?

Ṣiṣe akara oyinbo

Akara oyinbo wulo lawujọ lonii, paapaa lasiko igbeyawo, ayẹyẹ ọjọ ibi, isọmọlorukọ, iṣile, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Internet marketing ati Grapphics design

Iṣẹ Internet marketing ati Grapphics design jẹ ọkan pataki lara awọn iṣẹ to jawo julọ laye ode oni ti ọpọ nnkan ti n ṣẹlẹ lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Iṣẹ naa jẹ ọna lati maa ṣe ipolowo ọja lori ayelujara bii ori Facebook, Instagram, Twitter, Linkedin, apo ifiweranṣẹ email, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bii iwadii ileeṣẹ agbanisiṣẹ In deed, awọn to n ṣiṣẹ yii le ri owo to le ni $60,000 laarin ọdun kan.

Iṣẹ naa ko si ni nnkan ṣe pẹlu ibi ti eeyan wa nitori iṣẹ ori ayelujara ni.

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Website development

Anfaani iṣẹ yii ni pe eeyan ko nilo ọọfisi tabi ileeṣẹ kan gboogi lati bẹrẹ iṣẹ naa, bẹẹni eeyan ko nilo ju oṣu mẹta lati kọ iṣẹ ọhun lọ.

Ọpọlọpọ ẹkọ lo wa lori ikanni LinkedIn Learning, EDx, UDemy, Coursera, ati bẹẹ bẹẹ lọnipa bi eeyan ṣe le kọ iṣẹ 'Web development.'

Ile kikun ati ṣiṣe inu ile lọṣọ

Iṣẹ ile kikun ati iṣẹ ṣiṣẹ inu ile lọṣọ 'interior decoration' ko le lati mọ rara, bẹẹni eeyan ko nilo lati kawe ki o to mọ awọn iṣẹ naa.

Ifarajin fun iṣẹ

Ifarajin yii, tabi 'Volunteering' jẹ ọna abayọ fun awọn ti ko nifẹ si iṣẹ kikọ amọ ti wọn ko fẹ joko sile lati maa sun.

Eyii jẹ ọna lati maa ṣiṣẹ ti eeyan n kọ nile ẹkọ amọ ti ko ni maa gba owo oṣu.

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso

Anfani irufẹ ifarajin bayii ni pe akẹkọọ yoo tubọ ni imọ si nipa iṣẹ to n kọ nile ẹkọ.

Ẹ ma gbagbe pe kii ṣe awọn iṣẹ ti awọn akẹkọọ le kọ ree lasiko isinimi yii, a kan mẹnuba meje yii ni.

O le lọ kọ awọn ịṣẹ mii ti ọkan rẹ ba nifẹ si.