Bandits attacks in Zamfara: Àwọn agbébọn pa èèyàn 48 ní Zamfara, ọlọ́pàá, òṣìṣẹ́ sífú dìfẹǹsì wà lara wọn

Awoku ile kan tawọn agbebọn kọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko din ni eeyan mejidinlaadọta ti awọn agbebọn tun ti yibon pa lawọn ileto mẹta ni ipinlẹ Zamfara.

Awọn ileto naa ni ileto Sabon Gari Damri, ileto Damri gangan pẹlu ileto Kalahare.

Alamojuto ijọba ibilẹ Bakura, Aminu Suleiman ṣalaye pe awọn agbebọn naa ya bo awọn ileto naa lpọ yanturu bẹrẹ pẹlu ileto Sabon Gari Damri ni nnkan bii agogo meji ọsan ọjọ Ẹti.

Eeyan mẹsan la gbọ pe wọn pa nibẹ ki wọn to lọ si ileto Damri gangan funrarẹ nibi ti wọn ti pa eeyan mẹrin miran ninu eyi ti ọlọpaa kan pẹlu oṣẹ sifudifẹnsi kan wa.

Bakan naa lawọn ti iṣẹlẹ ṣoju wọn tun sọ pe awọn agbebọn naa tun dana sun ọkọ ọlọpaa kan, ti wọn si tun pa eeyan mẹjọ ni ileto Kalahe.

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Ileto naa wa laarin Sabon Gari Damri ati Damri.

Alamojuto kansu Bakura naa ṣalaye pe awọn agbebọn naa tun kọlu ileewosan kan nileto Damri nibiti wọn ti pa awọn eeyan kan to n gba itọju nibẹ.

Amọṣa o ni awọn ologun Naijiria ya bo wọn nilu Damri lẹyin ipe pajawiri awọn ara ilu kan ti wọn si doju ija kọ awọn agbebọn ọhun.

Eyi lo mu wọn sa asala lọ si Sabon Gari Damri nibi ti wọn pa eeyan mẹrindinlọgbọn.

Amọṣa o, awọn ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun lori ikọlu naa.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'