Gunmen Attack Jamb Staff: Òṣìṣẹ́ àjọ Jamb ní ilé ìtura tàwọn agbébọn ṣé ikọlù sí, àlàyé bo ṣé ṣẹlẹ rèé ní Ikorodu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Lọjọru to kọja yii, nise ni ọrọ di boolọ o yago mi nigba tawọn agbebọn kan yabo ile itura kan ni Ikorodu ti wọn si yinbọn pa ọlọdẹ wọn.
Iroyin taa ri gbọ ninu iwe iroyin ilẹ Naijriia Punch sọ pe arakunrin ọlọde ti wọn seku pa yi, orukọ rẹ a maa jẹ Peter ati pe ni agbegbe Owutu ni ile itura Mambillah ni isẹlẹ yi ti waye.
Punch jabọ pe nkan bi ago mẹta oru ku ogun isẹju lawọn agbebọn yi yabo ile itura naa ti wọn si ji awọn osisẹ ati alejo ile itura naa silẹ.
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Fí fún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
Lọkọọkan ejeeji lawọn alaburu yi bẹrẹ si ni wọ awọn yara lọ ti wọn si n gba nkan ini ati owo lọwọ awọn alejo ile itura naa.
Lara awọn ti wọn ja lole la gbọ pe awọn osisẹ ajọ eleto idanwo igbaniwọle si fasiti ni Naijiria, JAMB kan wa.
Nigba tawọn alaburu yi setan ti wọn fẹ maa lọ la gbọ pe ọlọde yi gbiyanju lati koju wọn.
Asiko yi la gbọ pe wọn yinbọn lu ẹni ogoji ọdun yi ti wọn si bẹ sinu ọkọ ti wọn si salọ kuro ni ile itura naa.
A tun gbọ pe awọn eeyan to wa nibẹ tara gbe ọlọdẹ naa lọ si ile iwosan sugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi rẹ ja si.
Ki ni ọlọpaa ati ajọ JAMB sọ nipa isẹlẹ wi
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko SP Benjamin Hundeyin, sọ pe awọn ti gbọ nipa isẹlẹ yi ati pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn to wa nidi rẹ.
Foonu,laptop,ẹgba ọrun ati awọn nkan olowo iyebiye wa lara nkan tawọn alaburu yi gba lọwọ awọn alejo to de si ile itura naa.
Okun to foju jọ ẹri nipa isẹlẹ yi ni fọnran fidio kan to gba oju opo ayelujarra instablog9ja kan.
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
Ninu rẹ la ti ri ti eeyan kan ti n pariwo pe oun dupẹ ẹmi ti ko bọ nitori awọn kan ja ilẹkun mọ awọn lori.
Bẹẹ la ri aworan awọn iyara ile itura taa si tun ri tawọn ọlọpaa kan gbe ibọn dani ni ita ile taa fura si pe o jẹ ile itura Mambillah yi.
A ko ribi fidi rẹ mulẹ ẹni to ya fọnran yi tabi ibi to ti wa.
Nipa awọn taa sọ saaju sọ tẹlẹ pe wọn jẹ osisẹ ajọ JAMB, ti wọn farakasa ninu isẹlẹ yi, ajọ naa ti fesi.
Alukoro JAMB Fabian Benjamin sọ pe lootọ lawọn osisẹ awọn wa ni ile itura naa sugbọn ko si ẹni to padanu ẹmi rẹ ninu isẹlẹ yi.


















