Fayemi declares for presidency: Kayode Fayemi sọ pé ètò ààbò ni yóò jẹ́ kókó nínú ìjọba òun

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gomina ipinlẹ Ekiti, to tun jẹ ẹni to fẹẹ dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ́ oselu All Progressives Congress, APC, Kayode Fayemi, ti sọ pe oun yoo mọ lé awọn ipilẹ isẹ ti Aarẹ Buhari fi lelẹ.
Fayemi sọ ọrọ yii lasiko to lọ si ipinlẹ Borno ati Yobe, lati beere fun atilẹyin awọn asoju ẹgbẹ́ APC, saaju idibo abẹnu.
Ninu ọrọ rẹ, o ni "ori aṣeyọri Aarẹ Muhammadu Buhari, la o mọ lé, a o si tete mojuto àwọn ibi to kù diẹ kaato si.
- Ilé tí mo kọ́ ni Ìlànà Omo Oòduà, mi ò lè sá kúrò níbẹ̀ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Okùnrin tó bá ọmọ ọdún 16 lòpọ̀, tó tún ya fọ́tò ìhòhò rẹ̀ dèrò àtìmọ́lé l’Ogun
- Mr Macaroni, Serap, Oby Ezekwesili, Amnesty International faraya lórí Deborah tí wọ́n pa ní Sokoto lórí ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ lódì sí Ànọ́bì
- Ìpàdé ìjọba Nàìjíríààti ASUU lórí ìyanṣẹ́lódì tún forí ṣánpọ́n
- Àwọ̀n ènìyàn rò pé wèrè, ajínigbé ni mí, àmọ́ mo ti kọ́ ilé janturu, fẹ́ ìyàwó mẹ́sàn àn , bí ọmọ 35 – Alfa to n ṣa irin ni atan
- Oloye Adeniji Ige, Mínísítà ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà dágbére fún ayé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún
- Ohun tí a mọ nípa ikọlù àwọn agbébọn sí ilé ìtura ní Ikorodu rèé
Fayemi sọ pe eto aabo ni yoo jẹ koko ninu iṣejọba oun, gẹgẹ bi ẹni to jẹ onimọ nipa eto aabo.
" Mo ni iwe ẹri imọ ijinlẹ ọmọwe ninu ẹ̀kọ́ nipa ogun jija, mo si sisẹ gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ ninu iṣejọba Aarẹ Obasanjo."
Bakan naa lo sọ pe ipa kekere kọ ni oun ko lati da alaafia pada lasiko ogun to waye ni Sierra Leone, Liberia, Rwanda, ati Sri Lanka.
O ni" a ti ni ilana ti ao lo lati mu alaafia wa fun àwọn eeyan wa, ka le ṣe iṣẹ́ agbẹ pẹlu ifọkanbalẹ, lọ sile ẹ̀kọ́ ni ifọkanbalẹ, ka si tun ma a gbe ninu alaafia."
Fayemi sọ pe ko si nkan to burú ki òun ṣe awọn nkan ti oun ṣe nilẹ okeere, fun orile-ede to fun oun ni ohun gbogbo.
Nigba to n fun Fayemi ni esi, alaga ẹgbẹ́ APC nipinlẹ Borno, Ali Bukar Dalori, sọ pe Fayemi ni awọn yan laayo nipinlẹ naa.
Nitori àwọn amuyẹ rẹ, ati nitori oore to ṣe fun awọn alaga ẹgbẹ́ naa ni gbogbo ipinlẹ labẹ isakoso oun.
Bukar Dalori sọ pe adari to nifẹ awọn eeyan rẹ lo le ṣe bẹẹ.
Bákan naa ni ọrọ ri nipinlẹ Yobe.
Igbakeji gomina to soju gomina Mai Mala Buni, sọ pe ti Fayemi ni àwọn n ṣe.
- Ó dàbí ẹni pé ẹ kò mọ̀ ìdí tí mo fi ń díje dupò ààrẹ, òhun rè é - Tinubu ṣàlàyé
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Fífún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
Fayemi jẹjẹ fun awọn aṣojú Yobe ti yoo dibo abẹnu pe ọna abayọ kiakia ni oun yoo wa si igbesunmọmi ati awọn rògbòdìyàn mii to n waye ni Naijiria.
Ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un, ọdun 2022, ni Gomina Kayode Fayemi kede ni gbangba pe oun naa yoo dupo aarẹ lati inu ẹgbẹ́ oselu APC lọdun 2023.
Saa kejì lo n lo lọwọ gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ekiti.




















