Top 10 hottest Countries: Wo àwọn órílẹ̀èdè mẹ́wàá ti ojú ọjọ́ wọn tí n gbóná jan-jan ju ti tẹ́lẹ̀ lọ

Aworan ile to gbona ju lagbay

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ kẹwàá oṣù karun ọdun yii ajọ to n ri si bi oju ọjọ ṣe ri lagbaye fi ikilọ sita pe o ṣeéṣe ki a koju ayika gbigbona ju ti isinyi lọ lọdun márùn ùn tó n bọ.

Àjọ naa sọ pe isọwọ gbona oju ọjọ yi yóò fi ọwọ kan lẹkun ju ti eyi táa n koju yi ti eleyi sí jẹ nkan to yẹ ká fura si.

Awọn onimọ sáyẹnsì tun sọ pe koda bi o ba kọja 1.5 degree Celsius lẹẹkan lọdun o le mú kí omi okun pọ jù tẹlẹ lọ ki eleyi sí fa omiyale.

Ajọ naa tẹsiwaju pe ṣiṣe nkan yi lodi sí adehun ti awọn orileede buwọ́lù lórí iyipada oju ọjọ ìyẹn Paris Climate agreement le se akoba ọlọjọ pipẹ f'ayika.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Ni oṣù Kẹrin awọn orileede bi Naijiria ati awọn alamuleti rẹ koju ooru to lagbara ju tateyinwa lọ tawọn ọmọ orileede naa si n ro pe ko si ibomiran to gbona ju ilẹ wọn lọ.

Ninu apilẹkọ iwadii BBC yi, a se agbeyẹwo awọn orileede to gbona julọ lagbaye latara akojọpọ iroyin ta ri lati ọdọ ikọ World Population Review lorileede Amẹrika.

Ki a kọkọ fi to yin leti pe loju opo wọn, a ri ti wọn ṣe agbekalẹ awọn orileede mẹwaa ti oju ọjọ gbona julọ lagbaye.

Naijiria ko si ninu wọn.

Ki wa ni wọn fi ṣe agbelewọn ti Naijiria ko fi si nibẹ?Akọkọ ni pe wọn wo bi o ṣe gbona wa latẹyinwa ti wọn si beere pe orileede wo lo gbona julọ lagbaye lọdun to kọja.

Bi a ba feyi wo, ao ri pe orileede Kuwait nibi ti oju ọjọ gbonba de 53.2 degrees Celsius ni ilu Nuwaiseeb lọjọ kejilelogun oṣu Kẹfa ọdun 2021.

Njẹ orileede yi ni akọsilẹ wa pe oju ọjọ ti gbona julọ ni inu itan? Labẹ eleyi, wọn sọ pe ni Amẹrika ni eleyi ti waye.

Death Valley ni California lọdun 1913 lakọsilẹ wa pe wọn ti ri ibi to gbona julọ pẹlu 56.7 degrees Celsius

Wọn tun beere pe ṣe igba ẹrun nikan ni agbegbe to gbona julọ maa n gbona tabi ni igba ọrinrin naa?

Wọn tun lo agbelewọn lati beere pe ṣe isọwọ bi oju ọjọ ṣe n gbona yi ti n waye lera laarin ọgbọn ọdun sẹyin?

Lẹyin ti wọn wo gbogbo awọn nkan wọnyi tan ni wọn wa sọ awọn orileede ti a ka kalẹ yi fun yin

Amin iyasọtọ kan

Awọn orileede ti oju oju ọjọ gbona julọ lagbaye laarin ọdun 1991 -2020

  • Mali - Oju ọjọ gbona de 28.83 ° C / 83.89 ° F in Celsius
  • Burkina Faso - Oju ọjọ gbona de 28.71 ° C / 83.68 ° Celsius
  • Senegal - Oju ọjọ gbona de 28.65 ° C / 83.57 ° F in Celsius
  • Tuvalu - Oju ọjọ gbona de28.45 ° C / 83.21 ° F in Celsius
  • Djibouti - Oju ọjọ gbona de 28.38 ° C / 83.08 ° F in Celsius
  • Mauritania - Oju ọjọ gbona de 28.34 ° C / 83.01 ° F in Celsius
  • Bahrain - 28.23 ° C / 82.81 ° F in Celsius
  • Palau - Oju ọjọ gbona de 28.04 ° C / 82.47 ° F in Celsius
  • Qatar - Oju ọjọ gbona de 28.02 ° C / 82.44 ° F in Celsius
  • Gambia - Oju ọjọ gbona de 27.97 ° C / 82.35 ° F in Celsius

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: