Deborah Samuel: Bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé

Deborah Samuel

Oríṣun àwòrán, Pexels/Sora Shimazaki

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Sokoto ti wọ́ àwọn afurasí méjì Bilyaminu Aliyu àti Aminu Hukunci lọ sílè ẹjọ́ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 fẹ́sùn lílọ́wọ́ nínú ikú akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Deborah Samuel.

Deborah Samuel tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìpele kejì ní ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni Shehu Shagari ìpínlẹ̀ Sokoto ni àwọn kan ṣekúpa fẹ́sùn wí pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ànọ́bì Muhammad.

Ilé ẹjọ́ Májísíréètì ìlú Sokoto ni Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá wọ́ àwọn afurasí náà tí àwọn náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún lọ.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀pọ̀ ìgbà l'èmí gan fẹ́ du àwọn ipò òṣèlú kan, bíì '2015, 2019' àmọ́ mo tẹ 'slow' torí bàbà mi, Akala náà ń jáde'

Olùpẹjọ́ fún ìjọba, Khalil Musa sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé ìwádìí ikú Deborah ṣì ń lọ lọ́wọ́ àti pé òkú rẹ̀ ṣì wà ní ilé ìgbókùúpamọ́sí ti ilé ìwòsàn olùkọ́ni ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Usman Danfodiyo, Sokoto.

Nígbà tó ń ṣáájú àwọn agbẹjọ́rò mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n tó ń gba ẹjọ́ rò fún àwọn afurasí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mansur Ibrahim bèèrè fún kí ilé ẹjọ́ fún àwọn afurasí náà ní ìdáǹdè.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Àwọn afurasí náà ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.

Àmọ́ adájọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà kọ̀ jálẹ̀ láti fún wọn ní ìdáǹdè tó sì pàṣẹ pé kí wọ́n fi àwọn afurasí náà sí àhámọ́ fún ìgbà kan ná.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ?

Deborah Samuel

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bo tilẹ jẹ pe awọn afurasi ti bẹbẹ, agbẹjọro fun ọlọpaa, Khalil Musa sọ fun ile ẹjọ pe awn ko tii pari iwadi awọn lori ọrọ yii.

O ṣalaye pe awọn ṣi lee mu awọn ẹsun mii wa sii si awọn afurasi ọhun lọrun.

Mansur Ibrahim to dari awọn agbẹjọro naa to fẹ ṣe oniduro fun awọn afurasi wa si ile ẹjọ lati wa bẹbẹ fun gbigba beeli wọn. O ni ki wọn da awọn afurasi naa silẹ lori idi pe "ka kan gba funra ẹni".

Lẹyin ifarahan nile ẹjọ, ile ẹjọ sun igbẹjọ naa si ọjọ mii ti wọn da lati wo ibeere fun beeli ti awọn agbẹjọro ti awọn afurasi n beere ti wọn yoo si fun wọn lesi.

Nigba ti wọn pari ni adajọ paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ sẹwọn.